Florence Babasola, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ ti ju ọmọkunrin ẹni ogun ọdun kan, Timilẹyin Amubiẹya, sẹwọn lori ẹsun pe o lu Akinrodoye Ọlakunle ni jibiti miliọnu meji aabọ naira (#2.5).
Inspẹkitọ Sunday Ọsanyintuyi to gbe olujẹjọ lọ sile-ẹjọ ṣalaye pe aago marun-un ku diẹ nirọlẹ ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii, lo huwa naa ni Aba Iya Gani, niluu Ileefẹ.
Ọsanyintuyi sọ pe ṣe ni olujẹjọ gba miliọnu meji aabọ lọwọ Ọlakunle pẹlu ileri pe oun yoo gbe ọkọ Lexus 350 LR funfun kan fun un, ṣugbọn ti ko ṣe bẹẹ.
O ni Timilẹyin ji owo Ọlakunle, o si sọ ọ di tiẹ, nitori naa, o ti huwa to lodi si abala okoodinnirinwo o din mẹta (383), irinwo o din mẹwaa (390) ati okoolenirinwo o din ẹyọ kan (419) ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Lẹyin ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun jibiti lilu ati ole jija ni agbẹjọro rẹ, Sunday Ọlagbaju, rawọ ẹbẹ si kootu lati faaye beeli silẹ fun un.
Adajọ Majisreeti naa, A. A. Adebayọ, sọ pe oun ko le fun olujẹjọ ni beeli afi ti agbẹjọro rẹ ba mu iwe wa nilana ofin. Titi igba naa, o paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Timilẹyin pamọ sọgba ẹwọn ilu Ile-Ifẹ titi di ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.