Ọga ọlọpaa patapata lorileede yii, Usman Alkali Baba, ti dabaa pe ki wọn jawee gbele-ẹ fun Igbakeji kọmiṣanna to tun jẹ ọga ni ẹka ti wọn ti n ṣewadii pataki lori iwa ọdaran, Abba Kyari, titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun riba gbigba ati lilẹdi apo pọ mọ ọdaran ti wọn fi kan an.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun yii, ni ọga ọlọpaa patapata naa kọwe si ileeṣẹ to n mojuto ọrọ awọn ọlọpaa lorileede yii, (Police Commission) pe ki wọn jawee gbele-ẹ fun ọlọpaa to maa n ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lori iwa ọdaran to ba le gidigidi yii. O fi kun un pe igbesẹ naa wa ni ibamu pẹlu ofin to de ifiyajẹni tileeṣẹ ọlọpaa n lo.
Bakan naa lo sọ pe bi wọn ṣe da a duro lẹnu iṣẹ fungba diẹ yii yoo fun igbimọ ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe kalẹ lati wadii iṣẹlẹ naa lanfaani lati le ṣiṣẹ wọn lai si idiwọ kankan.
Igbimọ ẹlẹni mẹrin ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe kalẹ lati ṣe agbeyẹwo iwe ti ilẹ Amerika fi ranṣẹ nipa ẹsun ti wọn fi kan Kyari lati ileeṣẹ to n wadii iwa ọdaran, iyẹn National Bereau of Investigation (FBI).
Awọn ọga ọlọpaa ni wọn ko jọ sinu igbimọ oluwadii ọhun. Igbakeji ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa to tun wa ni ẹka ẹka to n ri si iwa ọdaran, DIG Joseph Egbunike ni olori igbimọ ọhun.
Bakan naa ni igbimọ yii yoo gba ọrọ lẹnu Abba Kyari, toun naa yoo ṣalaye kinnikinni lori awọn ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an, ti awọn paapaa yoo si tẹsiwaju lati ṣe iwadi to ba yẹ si i. Lẹyin eyi ni awọn yoo gbe abọ iwadii yii fun awọn adari ileeṣẹ ọlọpaa lati le dari wọn lori igbesẹ to ba kan.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni ileeṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbaye, ẹka ti orileede Amẹrika, kede pe wọn n ile-ẹjọ kan ni Carlifonia n wa Abba Kyari, wọn lo lẹjọ ọ jẹ lori ọrọ ti ọmọ Naijiria kan ti wọn mu fun ẹsun jibiti, Ramon Abass, ti gbogbo eeyan mọ si Hushpuppi, sọ nipa rẹ lori jibiti kan ti ọmọkunrin naa lu ọkunrin oniṣowo kan ni orileede Dubai.