Nitori ẹsun tawọn kan fi kan Faṣọla lori ẹjọ Tinubu, ọkunrin naa binu gidigidi

Faith Adebọla

 Awuyewuye kan to n lọ nigboro, paapaa lori ẹrọ ayelujara lasiko yii ni bi wọn ṣe fẹsun kan minisita tẹlẹ fun iṣẹ ode ati ilegbee nilẹ wa, Babatunde Raji Faṣọla, pe iṣẹ abẹnu kan to n ṣe lọwọlọwọ bayii, ti ko si fẹ kẹnikẹni mọ nipa ẹ ni pe oun lo n kọ idajọ ti igbimọ onidaajọ ti wọn n gbọ awuyewuye to su yọ nibi eto idibo aarẹ ilẹ wa to kọja, iyẹn Presidential Election Petition Court (PEPC), yoo gbe kalẹ fun wọn, wọn ni Faṣọla lo n ba wọn wo apa ibi ti wọn yoo gbe idajọ naa gba.

Amọ Faṣọla, toun naa jẹ amofin agba, ati gomina ipinlẹ Eko nigba kan, ti bọ sita, ko si bọ sita lasan bẹẹ, o binu gidigidi ni pe irọ nla to jinna soootọ leyi ti wọn n pa mọ oun yii, o ni ko sohun to jọ bẹẹ, oun ko si ni ajọṣepọ kankan pẹlu eyikeyii ninu awọn adajọ maraarun ti wọn n gbọ ẹjọ naa, o lẹsun ibanilorukọjẹ ni wọn fi kan oun.

Ninu atẹjade kan ti Olubadamọran rẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Hakeem Bello, fi lede laṣaalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ yii, lo ti rọ awọn araalu lati ma ṣe feti si irọ tawọn ọbayejẹ ẹda kan n kulubọ rẹ kiri nipa oun.

Faṣọla ni ọrọ buruku to n ja ranyin ọhun ko le ṣẹyin awọn ọbayejẹ ẹda kan ti wọn o fẹ ki eto ijọba awa-ara-wa rẹsẹ walẹ lorileede yii, o ni ọta ilu gbaa ni wọn. O ni loootọ loun ko si niluu Abuja, amọ ki i ṣe pe oun ṣẹṣẹ kuro niluu naa, o ti ṣe diẹ, aisi larọọwọto oun ko si tumọ si pe idajọ toun ko mọ nnkan kan nipa ẹ loun n kọ nibi toun wa.

Bakan naa lo ni eyi ti wọn sọ nipa oun yii, oun o foju yẹpẹrẹ wo o, o ni oun ti bẹrẹ si i gbe igbesẹ bawọn agbofinro yoo ṣe ba oun tọpinpin awọn ti wọn gbe irọ buruku bẹẹ sori ẹrọ ayelujara, tori oun naa ri i ka lori ikanni abẹyẹfo tuita, to ti paarọ orukọ si ikanni “X” bayii, o si ya oun lẹnu, o bi oun ninu pẹlu.

O waa rọ awọn ọlọpaa lati ba oun fimu finlẹ, ki wọn wadii awọn to kọ ọrọ naa, ki wọn fi pampẹ ofin gbe wọn, koun le pade wọn ni kootu.

Leave a Reply