Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 ta a wa yii gẹgẹ bii ọjọ isinmi fun gbogbo oṣiṣẹ nitori eto idibo gomina to fẹẹ waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii kan naa.
Akọwe agba lọfiisi Olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni O. F. Ayọdele, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lalẹ Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kẹtala.
Ayọdele ni ijọba gbe igbesẹ yii lati le fun awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa lanfaani lati rinirin-ajo pada si agbegbe olukuluku wọn lati le lọọ ṣe ojuṣe wọn (iyẹn ibo didi) gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere.
Aaye isinmi yii lo ni ko yọ ẹnikẹni silẹ rara, gbogbo oṣiṣẹ pata lai fi ti ẹka yoowu ti wọn ti le maa ṣiṣẹ ṣe lo ni wọn gbọdọ jẹ anfaani nla yii.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yiim ni ajọ eleto idibo kede gẹgẹ bii ọjọ idibo sipo gomina nipinlẹ Ondo.
Lati ọjọ Isẹgun, Tusidee, ni ajọ ọhun ti kede pe awọn ohun eelo idibo ti wọn fẹẹ lo ti gunlẹ sẹpẹ si ileefowopamọ apapọ ilẹ wa to wa lagbegbe Alagbaka, niluu Akurẹ.