Nitori Funkẹ Akindele, awọn eeyan sọrọ buruku si Toyin Abraham

Monisọla Saka

Gẹgẹ bi eto ifami-ẹyẹ dani lọla ti ileeṣẹ Multichoice ṣagbekalẹ rẹ, iyẹn African Magic Viewers Choice Award (AMVCA), ẹlẹkẹẹwa rẹ, to waye lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, ṣe wa sopin ni gbọngan ayẹyẹ Eko Hotel and Suites, awọn eeyan ti tun n sọko ọrọ si oṣere-binrin ilẹ wa nni, Toyin Abraham lori ayelujara.

Niṣe ni wọn n sọrọ buruku si obinrin ti wọn n pe ni Mama Ire yii, awọn orukọ bii alabosi, ọlọtẹ ati daleru daleru ni wọn si n pe e, eyi ko si ju nitori ọrọ gbajumọ oṣerebinrin nla nni, Funkẹ Akindele, ti wọn n pe ni Jẹnifa, ti wọn ti jọ ni ikunsinu tẹlẹ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe fiimu Akindele to ṣe kẹyin, ‘A Tribe Called Judah’, to si jẹ oun lo pawo ju nilẹ Naijiria ati Afrika latigba ti wọn ti n gbe fiimu naa lọ si sinnima, ko jẹ itẹwọgba fawọn oludari eto AMVCA, bẹẹ ni wọn ko fun Funkẹ tabi ẹnikẹni ninu awọn akopa naa ni awọọdu kan bo ti wu ko mọ.

Eyi lo ka pupọ awọn eeyan lara, ti wọn ni ojooro ni wọn fi ṣeto ọhun gẹgẹ bi wọn ṣe gbe e fun fiimu ‘Breath of Life’. Lasiko tawọn eeyan n fapa janu lori eyi lọwọ ni Toyin Abraham ti aawọ ati ikunsinu aarin oun ati Funkẹ ṣẹṣẹ n lọ si okun igbagbe kọ ọrọ idupẹ ranṣẹ si Arabinrin Busọla Tẹjumọla, ti i ṣe olori ileeṣẹ Multichoice, ti wọn jẹ alakooso eto awọọdu AMVCA, to maa n waye lọdọọdun.

Toyin to sọ pe eto naa yatọ lọdun yii, nitori ti wọn ko gbe ojo fun Aina, bi gbogbo rẹ ṣe yẹ ko lọ lo ṣe lọ, awọn ti ami-ẹyẹ tọ si ni wọn si gba a. Eyi ni awọn eeyan fi gba ya a pe Funkẹ Akindele lo n fi ṣe yẹyẹ.

Bo tilẹ jẹ pe o ti pa ọrọ to mu kawọn eeyan binu si i yi rẹ loju opo ayelujara rẹ, ohun ti Toyin kọ sibẹ niyi, “Awọọdu AMVCA to dara, to si jẹ otitọ ju lọ latijọ yii wa niyi. Ẹ kuuṣẹ, Arabinrin Busọla Tẹjumọla. Ẹ ṣe daadaa, bẹẹ si ni, a nifẹẹ yin. Africa Magic lapapọ, ẹ kuuṣẹ o”.

Itara ati ọna lati fi orogun rẹ nidii iṣẹ tiata, iyẹn Funkẹ Akindele ṣe ẹlẹya ni awọn eeyan ka ọrọ ẹ si, wọn ko si ba a mu un ni kekere. Ariwo ọrọ yii to pọ, ti kaluku fi n sọrọ buruku si i, lo mu ki Toyin sare pa ọrọ naa rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ija ikunsinu ati ija abẹnu ti n lọ laarin awọn oṣerebinrin mejeeji yii tẹlẹ.

Bo si tilẹ jẹ pe awọn ko kora wọn sita bii ọmọ ọjọ mẹjọ, yala lori ayelujara tabi loju aye gẹgẹ bi ọpọ awọn obinrin onitiata ti wọn n ba ara wọn ja ṣe maa n ṣe, sibẹ, ija to foju han, ti awọn ololufẹ awọn mejeeji si tubọ mu ki o fẹju si i ni.

Koko ohun to si n faja awọn oṣere mejeeji ko ju orogun owo lọ. Oṣu Kejila, ọdun 2021, ni Funkẹ kede pe sinnima oun, iyẹn ‘Ọmọ ghetto the saga’ yoo wọ sinnima. Asiko yii kan naani wọn gbe fiimu Toyin Abraham, ‘Ghost And the Tout’ naa jade.

Awọn eeyan bẹrẹ si i bu Toyin pe o mọ-ọn-mọ gbe fiimu rẹ si asiko naa lati din owo to yẹ ki Funkẹ pa ku ni. Nigbẹyin gbẹyin, wọn fẹnu ṣaata fiimu Toyin yii ni.

Lọdun to tẹle e bakan naa, iyẹn loṣu Kejila, ọdun 2022, ni ‘Battle on the Buka Street’, ti Funkẹ ṣe, to si jẹ itẹwọgba fawọn eeyan gidi gan-an, asiko yii naa ni ‘Ijakumọ’ ti Toyin ṣe jade sita.

Bakan naa ni ọrọ ri lọdun to kọja yii, iyẹn 2023, nigba ti fiimu awọn mejeeji jọ wọ sinnima fun wiwo nigba kan naa, iyẹn ‘A Tribe Called Judah’ lati ọwọ Funkẹ, ati ‘Malaika’ lati ọwọ Toyin Abraham.

Ni gbogbo igba ti wọn ti jọ n pade pọ yii, Funkẹ lo maa n rọwọ mu ju, awọn eeyan si maa n tori ẹ bu Toyin pe ẹni to yẹ ko fara balẹ kọṣẹ lọwọ ẹ lo n ba ta kanngbọn.

Ni nnkan bii ọsẹ meji si asiko yii ni Toyin gbe itiju ta, to si kọ awọn ọrọ didun nipa Funkẹ Akindele. O fidi ẹ mulẹ pe awọn eeyan, paapaa ju lọ awọn ololufẹ awọn atawọn ọrọ gbọ yii sọ yii, lo maa n daja silẹ laarin awọn. O jẹwọ pe ẹgbọn ati ọga oun ni Funkẹ n ṣe, ati pe nọmba waanu, ti wọn n wo kọ’ṣe ni laarin awọn oṣerebinrin.

Ọrọ iwuri yii mu ki Funkẹ fesi si ọrọ ẹ pẹlu ami ifẹ ati idupẹ.

Bakan naa ni Toyin ki Funkẹ lọjọ ibi rẹ to ṣe kẹyin, ti tọhun naa si se bẹẹ lasiko ti Toyin naa.

Eyi lo jẹ ki awọn eeyan ro pe o ti fopin si ija abẹnu wọn.

Afi bi wọn ṣe tun ri ọrọ ti Toyin kọ, nigba ti Funkẹ ko si ri ẹyọ awọọdu kan mu lọ sile bi fiimu rẹ ṣe rin to, oun ni wọn fẹsun rẹ kan Toyin pe o n fọgbọn ta si.

Leave a Reply