Dada Ajikanje
Titi di bi a ṣe n ko iroyin yii jọ lawọn eeyan to n gbe ni Doyin, lagbegbe Orile, l’Ekoo, ṣi wa ninu ibẹru-bojo pẹlu bi awọn onimọto ṣe kọju ija buruku sira wọn lati ọjọ Iṣẹgun, titi di owurọ kutu oni.
ALAROYE gbọ pe gareeji ti awọn kan fẹẹ fagidi gba lagbegbe ọhun lo da ija yii silẹ laarin wọn, nibi ti wọn ti ṣa ẹlomi-in ladaa, ti wọn si tun yinbọn pẹlu.
Gbogbo awọn adugbo wọnyi; Doyin-Orile, Alagba, Orowumi, Coker ati Ọpẹloyẹru ni wahala ọhun de, ti awọn eeyan ko si le foju kan oorun.
Ọkunrin gbajumọ sọrọsọrọ ori redio to n gbe lagbegbe ọhun salaye pe, “Ẹni kan ni wọn sọ pe asiko ẹ ti to lati gbe gareeji ibi to ti n gba owo silẹ, ṣugbọn to kọ lati ṣe e, bi awọn eeyan kan ti inu n bi, t’awọn naa fẹẹ gba gareeji ọhun ṣe kọju ija sawọn ti ko fẹẹ fi gareeji silẹ niyẹn, nni walaha ba gba gbogbo adugbo kan.”
O fi kun un pe awọn ṣọja kan to n kọja ni wọn kọkọ pana rogbodiyan ọhun ni kete to bẹrẹ lana-an, ṣugbọn nigba to dọwọ aṣaalẹ ni wọn tun bẹrẹ pada, ti wọn si yinbọn mọju.
Ṣiwaju si i, a gbọ pe bi ilẹ ṣe mọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ni wọn ti bẹrẹ wahala ọhun pada, ti ọlọja ko le patẹ, tawọn oniṣowo mi-in paapaa ko le ṣi ṣọọbu wọn lagbegbe naa ni Doyin-Orile.
Wọn ni niṣe lawọn janduku kan n lo anfaani wahala yii fi ja foonu ati owo gba lọwọ awọn eeyan, ti idarudapọ gidi si gba gbogbo agbegbe ọhun kan.
Ọkunrin oniṣowo kan naa wa lara awọn eeyan ti wọn kọ lu lagbegbe Orowunmi. Ninu ṣọọbu ẹ ni wọn ti lọọ ba a ti wọn si ṣe e leṣe, bẹẹ ni wọn tun ko o lowo ati foonu lọ.
ALAROYE pe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekoo, Ọgbẹni Muyiwa Adéjọbí, o ni loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, bẹẹ nileeṣẹ ọlọpaa ko dakẹ lori ọrọ ọhun.