Ẹgbẹ awọn onimọto da wahala silẹ l’Ado-Ekiti

 Taofeek Surdiq,  Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ti fi panpẹ ofin mu mẹta ninu awọn oloye ẹgbẹ awọn onimọto ti wọn n pe ni RTEAN nipinlẹ Ekiti, lori rogbodiyan to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa yii.

Laaarọ Ọjọbọ, Tosidee, ni gbogbo igboro Ado-Ekiti daru pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ Roodu ṣe ya bo ibudokọ kan to wa laduugbo Okeyinmi, ti wọn si n yinbọn lakọlakọ.

Eyi lo fa a ti gbogbo awọn eeyan fi bẹrẹ si i sa kijokijo, odidi ogoji iṣẹju ni rogbodiyan yii fi waye, ti olukuluku si n di ori rẹ mu pẹlu bi ojo ibọn ṣe n rọ.

Nigba t’ALAROYE de agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, gbogbo ibẹ lo dake rọrọ, ti awọn oṣiṣẹ ijọba to fẹẹ lọ si ibi iṣẹ ko si ri ọkọ tabi ọkada gbe wọn lọ.

Awọn ẹgbẹ Roodu naa ti n ja lati bii ọsẹ meji sẹyin lori ẹni ti yoo wa lori oye ni kete ti gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan bagori aleefa.

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa to jẹ ti igun Ọgbẹni Jide Ọmọlẹyẹ ni wọn ko ibọn atawọn ohun ija mi-in, ti wọn si ya bo ibudokọ kan to wa laduugbo Okeyinmi.

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ba ALAROYE sọrọ ṣalaye pe Jide Ọmọlẹyẹ lo ṣiṣẹ takuntakun fun gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Biodun Oyebanji, lakooko eto idibo to kọja.

Eyi ni wọn sọ pe o fa a ti awọn igun Ọmọlẹyẹ ṣe fẹẹ gba ipo lọwọ Ọgbẹni Farotimi Ọsho to wa lori ipo alaga ẹgbẹ Roodu lọwọlọwọ.

Abutu sọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii to peye lori ọrọ naa pẹlu bi wọn ṣe pe bii mẹta ninu awọn oloye ẹgbẹ ọhun lati waa ṣalaye ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa.

O ni awọn agbofinro yoo ṣe ohun gbogbo lati ri i pe wọn wadii iṣẹlẹ to da jinnijinni silẹ ni gbogbo igboro ilu Ado-Ekiti ati ayika rẹ.

Leave a Reply