Bi ko je awon ọlọpaa Eko ti won wa nitosi, eyi ti a n wi yii kọ la ba maa wi o. Ọkunrin oniṣowo kan, Abiọdun Adeyinka, iba ma ti bomi lọ lasiko ọdun Ileya to kọja yii. Aarin afara to lọ si Eko lati Oworonṣoki ti wọn n pe ni ‘Third Mainland Bridge’ lo duro si, nibi lo ti fẹẹ bẹ sọsa, ko too di pe awọn ọlọpaa ra a mu. Awọn ọlọpaa ti ri i pe o n rin kọ́rọkọ̀rọ lori afara yii, awọn naa si ti bẹre si i fi oju ẹgbẹ kan ṣọ ọ, igba to n nasẹ siwaju pe ko di ‘ṣọru’ ninu omi ọsa yii lawọn ọlọpaa yii sare si i.
Nigba ti wọn mu un pe bawo lọrọ ṣe ri, Abiọdun ni ouo yawo kan ni, pe oun yawo lọdọ awọn gbọmu-le-lanta, owo gba-a-ko-o da-a-pada-kia-pẹlu-ele. O ni oun fẹẹ sare fi owo naa ṣe iṣẹ kan ni, ẹgbẹrun lọna irinwo din mẹwaa (N390,000) si lowo naa to ya lọdọ wọn. Ṣugbọn ọkunrin yii ni iṣẹ ti oun fi owo ṣe lugbadi, adanu lo si ti ibẹ jade. Awọn ti wọn ya a lowo ko fẹẹ gbọ iru alaye bayii, oun ree ko si rowo san mọ. Ohun to ṣe ro o paapaapaa ree, lo ba kuro ni ile rẹ ni Ikọtun, o di ori biriiji ‘Third Mainland’, nibi to ti fẹẹ bẹ somi.
O ti wa lọdọ awon ọlọpaa o. Wọn ni awọn n ṣe iwaasu fun un ni pe bi a o ku iṣe ko tan, ko si nnkan to yẹ ko ṣe ẹda ti yo fi fibinu bẹ sọsa, ti yoo ni ki oun ba odo lọ lo dara.