Nitori gbese, Ọlaide ta ọmọ-bibi inu ẹ lẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira

Faith Adebọla ati Ismaeel Adeẹyọ

 Loootọ lawọn eeyan maa n gbadura pe ipọnju ti yoo mu awọn jẹ ounjẹ ọta awọn, k’Ọlọrun ma jẹ kawọn ri’ru ẹ, amọ eyi to ṣẹlẹ si iyaale ile ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ti wọn porukọ ẹ ni Ọlaide Adekunle yii kọja wẹrẹwẹrẹ o, tori eleyii le ju keeyan jẹ ounjẹ ọta ẹni lọ. Niṣe lobinrin yii lu ọmọ-bibi inu rẹ, Moridiat Rasaq, ọmọbinrin to ṣẹṣẹ pe ọmọ ọdun kan aabọ pere ta ni gbanjo, ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (N600,000) lo  ta a. O ni tori ati san gbese owo banki alabọọde kan toun ya, ti wọn si ti n fooro ẹmi oun nitori ẹ, iyẹn owo ti wọn maa n fi ẹfẹ pe ni gbọmu-le-lanta, tori ọrọ gbese naa loun fi ṣepinnu buruku yii.

Ọlaide yii ni wọn loun ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Nureni Rasaq, jọ n gbe niluu Sango, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun.

Ọkọ obinrin ọhun lo mẹjọ lọ si tọlọpaa, ni ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Sango, gẹgẹ bii alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin yii.

Wọn lọkunrin naa sọ pe iyawo oun gbe ọmọ awọn torukọ rẹ n jẹ Mọridiat Rasaq yii lọ siluu Eko lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023, o loun fẹẹ lọọ ṣe ọrọ-aje, boya oun yoo ri iṣẹ ṣe lati fi ri owo diẹ, o si to ọsẹ meji mẹta to lo lọhun-un ko too pada. Ṣugbọn nigba ti yoo fi pada de, Ọlaide nikan lo pada, ko sọmọ to pọn sẹyin lẹyin ẹ mọ, abiyamọ lo ba jade, sisi lo ba pada wọle.

O lọrọ naa ṣe oun ni kayeefi, oun si beere ibi tọmọ awọn wa, o kọkọ n purọ oriṣiiiriṣii foun, nigba to ya ni ko tiẹ da oun lohun mọ, ko fesi sibeere oun mọ, niṣe lo fi oun atawọn ti wọn gbọ si ọrọ naa gun lagidi.

O ni titaku tobinrin yii taku lati sọ ibi tọmọ naa wa lo mu koun mẹjọ rẹ wa si teṣan, tori ọrọ naa toju su oun.

Lọgan ti awọn ọlọpaa gbọ ẹsun yii ni DPO teṣan Sango, CSP Dahiru Saleh, ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ rẹ lati lọọ fi pampẹ ofin gbe Ọlaide lẹyẹ-o-sọka.

Ṣe wọn ni ile iku la a ti i jẹwọ arun, nigba tobinrin yii de akata awọn ọtẹlẹmuyẹ, awọn ọmọran ti i moyun igbin ninu ikarawun, lo ba jẹwọ fun wọn pe oun ta ọmọ oun ti wọn n wa ọhun ni. O lẹnikan loun ta a fun niluu Eko toun ṣọrọ-aje lọ, ati pe gbogbo owo toun ta ọmọ naa ko ju ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (N600,000) lọ.

Obinrin yii ṣalaye pe ọrọ lo ba mo ko mo ro waa foun, ki i ṣe pe oun deede ya ọdaju bẹẹ o, amọ ipọnju lo mu koun gbe itiju ta, toun fi pinnu lati ṣe ohun toun ṣe, o ni gbese lo n le oun kiri, oun ya owo lọwọ banki alabọọde kan ni, ọsọọsẹ lawọn si gbọdọ maa da gbese naa pada, amọ nnkan toun tori ẹ yawo ko bọ si i, gbogbo ọgbọn toun da lo ja si pabo, Ki oun si too ṣẹju pẹu, ọsẹ kan yoo ti pe, eyi lo mu koun di isansa ati alarinkiri lọsọọsẹ, amọ nigba to ya, awọn oṣiṣẹ banki toun jẹ lowo ko jẹ koun rimu mi, bi wọn ṣe n dunkooko m’oun ni wọn n fẹjọ oun sun kaakiri, eyi lo mu koun kori siluu Eko lati lọọ gba aaru.

O ni l’Ekoo, oun kiri omi Piọ wọta tutu, ibi toun ba si ri loun n sun, nibi toun ti n fori polẹ kiri loun ti ṣalaabapade ẹnikan to gba oun lamọran nigba toun sọ ipenija gbese to doju kọ oun fun un, ẹni yii lo gba oun lamọran pe koun kuku ta ọmọ ọwọ oun, oun si gba, n lọkunrin naa ba mu oun lọọ ba obinrin kan to ra ọmọ naa lọwọ oun, to si foun lowo.

Wọn beere ibi tobinrin to ta ọmọ ọhun fun wa, o loun ko mọ, wọn tun wa ọkunrin to fi i mọna ọdọ ẹni to ra ọmọọlọmọ ọhun, wọn o ri iyẹn naa, gbogbo wọn ti poora bii iso.

Ṣa, Adele Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DCP Babakura Muhammed, ti paṣẹ ki wọn taari afurasi ọdaran yii lọ sẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweeran, l’Abẹokuta, fun iwadi to lọọrin.

Bẹẹ si lawọn ọtẹlẹmuyẹ ṣi n tọpinpin ibi ti ikoko yii wọlẹ si, ki wọn le doola ẹmi ọmọ ọhun.

Lẹyin iwadii ni wọn lawọn yoo foju abiyamọ ọran yii atawọn to lọwọ ninu iwakiwa ọhun bale-ẹjọ, ki wọn le lọọ gba ijiya to ba tọ si kaluku wọn.

Leave a Reply