Nitori iṣekuṣe, adajọ ran Jimọh lẹwọn gbere

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ gíga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki baba ẹni ọdun mejilelọgọta kan, Daudu Jimoh, maa lọ sẹwon gbere lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an lo pọ ni Ilupeju-Ekiti.

Ọdaran naa ni wọn gbe wa siwaju adajọ Lẹkan Ogunmoye, lọjọ karun-un, oṣun Kẹjọ, ọdun 2020, pẹlu ẹsun ẹyọ kan to rọ mọ ifipa ba eeyan lo pọ.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun naa ṣe sọ, o ni Daudu Jimoh fipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an kan lo pọ, ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2019, ni Ilupeju-Ekiti. Ẹsun yii ni wọn sọ pe o lodi sofin ifipabanilopọ ti wọn kọ ni ipinlẹ Ekiti lọdun 2012.

Ninu ẹri rẹ lasiko igbẹjọ naa, ọmọdebinrin naa to jẹ ọmọ ile-iwe alakọọbẹrẹ ni Ilupeju-Ekiti, ṣalaye pe ọdaran naa ti gbogbo eeyan mọ si (Baba Kula) to jẹ lanlọọdu awọn ti fipa ba oun lo pọ bii igba mẹrin ki ẹgbọn oun obinrin too ri awọn, to si tu aṣiri awọn lọjọ naa.

Ọmọdebinrin naa sọ pe “Baba Kula lo pe mi sí yara rẹ, to sì sọ pe ki n sun sori aga nla kan to wa ninu yara rẹ, o si bọ gbogbo aṣọ mi, lẹyin naa lo fipa ba mi lo pọ, bi ẹgbọn mi ṣe ri wa lo sọ fun iya mi.”

“Ni gbogbo igba to ba ti fipa ba mi lo pọ ni ẹru maa n ba mi lati sọ fun iya mi tabi ẹgbọn mi obinrin, nitori o ti sọ fun mi pe n ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni ayafi ti mo ba fẹẹ ku.”

Lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ, Agbefọba, Ọgbẹni Julius Ajibare, ko iwe ti wọn fi gba oun silẹ lẹnu ọmọdebinrin naa ati esi abajade ilera ọmọdebinrin naa wa siwaju adajọ.

Nigba ti ọdaran naa sọrọ lati ẹnu agbẹjọro rẹ, Chris Omokhafe, o jẹwọ pe loootọ ni oníbara oun ṣẹ ẹṣẹ naa.

Ninu idajọ rẹ , Onidajọ Lekan Ogunmoye, sọ pe ninu iwe ti wọn fi gba oun silẹ lati ẹnu ọdaran naa ati ọrọ rẹ ni ile-ẹjọ, o fihan pe ọdaran naa ṣẹ ẹẹẹ yii.

O waa paṣẹ pe ki ọdaran naa maa lọ si ẹwọn gbere, pẹlu iṣẹ aṣekara.

 

 

Leave a Reply