Gbenga Amos
Giri-giri ẹsẹ ati eruku to n sọ lala ko jẹ ki ẹnikan bikita fẹnikeji lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to lọ yii, nigba tawọn araalu Shimfida, bẹrẹ si i sa kuro niluu, nitori ibẹru ati ewu awọn agbebọn to n yọ wọn lẹnu. Nigba ti eruku yoo si fi rọlẹ, oku ọmọ meje lawọn eeyan naa ri nilẹ, niṣe ni wọn tẹ wọn pa.
Ohun meji lo mu kawọn eeyan ilu naa ṣiyan ti wọn ko si duro gbọbẹ. Akọkọ ni pe lojiji ni wọn ṣadeede ri i pe awọn ṣọja ati awọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wọn gbẹkẹle fun aabo lagbegbe naa ṣadeede kuro lawọn ibi ti wọn maa n duro si, wọn o si ri awọn to n ṣe patiroolu kiri igboro ninu wọn mọ, bẹẹ ni wọn lawọn ṣọja naa o dagbere fẹnikan ti wọn fi lọ.
Nibi ti wọn ti n woye boya awọn ṣọja yii maa too pada de ki ilẹ ọjọ naa too ṣu ni wọn ṣadeede gburo ibọn, ti iro ibọn naa si pọ, wọn ni niṣe lo da bii pe awọn janduku agbebọn ti gbọna ẹburu yọ si wọn, lọrọ ba di bo-o-lọ-o yago, ko sẹni to duro wo ohun to n le wọn ki wọn too ki ere mọlẹ.
Asiko tọlọmọ o mọ ọmọ ẹ mọ yii ni wọn lawọn ọmọde naa ti ṣubu nibi ti wọn ti n sare laarin ero, ko si sẹni to duro ṣaajo wọn, niṣe ni kaluku n sa asala fẹmi-in ẹ lọ.
Ọgbẹni Kabir Haruna, kansẹlọ ilu Shimfida, nijọba ibilẹ Jibia, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe “bawọn ọmoogun ṣe wa lagbegbe yii lo jẹ kawọn eeyan ṣi wa niluu, lai fi ti pe awọn agbebọn ko jẹ ki wọn sun gbadun, ṣe.
“Ṣugbọn nigba ti wọn o ri ẹṣọ alaabo mọ lojiji, to jẹ iro ibọn ni wọn n gbọ lati okeere, eyi lo fa idarudapọ naa, wọn lero pe awọn agbebọn ni.
“Ọpọ awọn araalu naa ni wọn ti sa lọ si agbegbe Tasha Furera, ileewe kan niluu Jibia lawọn mi-in fori pamọ si, awọn mi-in si lọ siluu Gurbin Baure.”
Wọn lawọn ọlọpaa ko ti i fesi kan lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn wọn ti ko oku awọn ọmọde naa, wọn si ti lọọ sin wọn.