Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lati le fun awọn oludibo lanfaani lati lọ kaakiri awọn ilu ti wọn ti fẹẹ dibo, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti kede ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Atẹjade kan ti Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Teslim Igbalaye, fi sita jẹ ko di mimọ pe ọlude naa wa lati le jẹ ki awọn araalu ṣe ojuṣe wọn ninu idibo naa. O ni yoo fun awọn to ba fẹẹ rin irinajo lọ si ibi ti wọn ba ti fẹẹ dibo lanfaani lati ṣe bẹẹ.
Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ni eto idibo aarẹ orileede Naijiria, idibo awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin ati ti awọn aṣofin agba yoo waye kaakiri orileede yii.
Igbalaye ke si awọn oṣiṣẹ ijọba lati lo ọjọ Ẹti, Furaidee, naa lati rinrin-ajo lọ sawọn ibudo idibo wọn, ki wọn le dibo nibaamu pẹlu alakalẹ ofin orileede yii.
O waa ke si gbogbo awọn araalu lati bọwọ fun ofin lasiko idibo ọjọ Satide ati eyi ti yoo waye loṣu Kẹta, ọdun yii.