Monisọla Saka
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nijọba ilẹ UK ṣekilọ fawọn ọmọ ilu wọn lori ikọlu nla tawọn afẹmiṣofo fẹẹ ṣe l’Amẹrika laipẹ yii.
Oludmọran lori ọrọ eto irinna lorilẹ-ede naa lo sọ pe o ṣee ṣe kawọn ọdaju ẹda naa kọ lu ilẹ Amẹrika. O le kan ẹnikẹni, to fi mọ ibi tawọn alejo maa n wa, awọn ibi tero maa n pọ si ati ibi tawọn ero to n duro de mọto maa n duro si.
Wọn ni ki wọn feti leko si iroyin, ki wọn si wa ni igbaradi loorekoore.
Boya lo ti i le ju ọsẹ kan lẹyin tawọn orilẹ-ede UK ati US sin ilẹ Naijiria ni gbẹrẹ ipakọ lori ikọlu to ṣee ṣe kawọn ẹni ibi ọhun ṣe lolu ilu orilẹ-ede wa.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, “Iṣẹ adajẹ ni ẹni to fẹẹ kogun ja US yii maa jẹ, o le jẹ eeyan kan tawọn afẹmiṣofo ọhun ti tọwọ bọ lọpọlọ, ti ko le da ronu funra ẹ mọ, ti wọn waa ki i laya lati doju ija kọ ogunlọgọ awọn eeyan bẹẹ, agaga ita gbangba tawọn eeyan maa n pọ si ti wọn ti foju sun pe ibẹ lawọn ti maa ṣọṣẹ. Bẹẹ ikọlu yii le waye lai jẹ pe ẹnikẹni mọ tabi gbọ nnkan kan ṣaaju ẹ”.
Lẹyin ti wọn pe awọn eeyan si akiyesi yii nijọba ilẹ UK sọ pe o ṣee ṣe ki wọn ko awọn ẹṣọ alaabo sawọn ibi igbafẹ ati ibi tero maa n pọ si nilẹ Amẹrika lati le dena ikọlu naa.
O ni,” Ẹka ileeṣẹ eleto aabo, Homeland Security Services, ti ṣi awọn eeyan leti lori awọn nnkan ti wọn le maa ri bii ami tabi idunkooko pe nnkan fẹẹ ṣẹlẹ. Nidii eyi ni wọn ṣe n reti awọn agbofinro atawọn ẹṣọ eleto aabo to fẹsẹ rinlẹ daadaa lawọn gbagede ati ibi ayẹyẹ gbogbo. Bakan naa ni wọn tun le maa dena ẹni to maa wọle tabi jade lawọn ibi kan, wọn si tun le maa yẹ inu baagi awọn eeyan wọn wo pẹlu ohun eelo igbalode ti wọn fi n yẹ ẹru wo”.