Nitori ilaji owo-oṣu tijọba san fun wọn, ẹgbẹ olukọ Fasiti Eko ṣewọde

Ẹgbẹ awọn olukọ ileewe giga yunifasiti, ẹka ti Yunifasiti Eko, ti ṣe iwọde lori ilaji owo-oṣu ti wọn san fun wọn lẹyin ti wọn fopin si iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ ti wọn gun le lati inu oṣu Keji, ọdun yii.  Awọn olukọ naa, eyi ti awọn akẹkọọ ileewe wọn pẹlu darapọ mọ wọn lati fẹhonu han ta ko bi wọn ṣe san owo-oṣu ilaji fawọn olukọ wọn ninu oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Wọn ni awọn o ki i  ṣe arebipa to n tọrọ owo, iṣẹ oogun oju awọn lawọn n jẹ. Bẹẹ nijọba ko ba awọn sọ ọ pe ilaji owo-oṣu ni wọn maa fun awọn.

Okan-o-jọkan akọle ni awọn eeyan naa gbe lọwọ lati fi ẹhonu wọn han. Lara rẹ ni, ‘Ko si owo, ko si iṣẹ’. Ngige, yee rẹ awọn olukọ jẹ’ ‘Awọn olukọ lo n kọ orileede, ṣugbọn Ngige n rẹ wọn jẹ’.  ‘Eto ẹkọ fasiti ki i ṣe ibi ojubọ, Ngige, jawọ nibẹ’.  Eleyii ati oriṣiiriṣii akọle mi-in ni wọn gbe lọwọ ti wọn fi n fẹhonu han ta ko igbesẹ ijọba apapọ yii.

Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni wọn san owo-oṣu oṣu Kẹwaa fun wọn, iyalẹnu lo si jẹ fun awọn olukọ naa nigba ti wọn ri i pe aabọ owo ni wọn fun wọn.

Bakan naa ni Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, sọ pe ko pọn dandan ki ijọba san owo-oṣu fawọn oṣiṣẹ lasiko ti wọn ba fẹhonu han ti wọn ko ṣiṣẹ kankan. Bo tilẹ jẹ pe awọn oloye ẹgbẹ awọn olukọ yii ṣepade lẹyin ti wọn gba aabọ owo-oṣu yii, sibẹ, wọn ni awọn ti pinnu pe awọn ko ni i tori eyi daṣẹ silẹ.

Ṣugbọn pẹlu iwọde ti wọn tun ṣe yii, ko sẹni to ti i le sọ boya wọn yoo tun ero wọn pa.

Leave a Reply