*Awọn ọmọ Buhari pẹlu awọn ọmọ Tinubu ni o
Ademọla Adejare
Ni ọjo Ẹti, Furaide, to kọja yii, gbogbo ẹni to ba wa nibi isinku akọbi ọmọ Awolọwọ lobinrin, Arabinrin Tọla Oyediran, yoo mọ pe oju n kan Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nitori ara rẹ ko lelẹ kan dan-in dan-in. Isin ti lọ jinna ko too de sibi ayẹyẹ naa, nigba to si di pe wọn tun n kọrin lẹẹkeji lẹyin to de lo dide, bo si ti dide ni Oloye Bisi Akande naa dide tọ ọ, ṣe gẹrẹrẹ ni agbẹ n wọ tọ ọkọ ẹ lẹyin, igbin ki i re ajo ko fi ile rẹ sẹyin, ibi ti Tinubu ba n lọ, Akande yoo wa lẹyin rẹ dandan ni. Bi eeyan ba si ti ri Tinubu, to ri Akande lẹyin rẹ gbagbaagba, ki tọhun ti mọ pe ọrọ naa lọwọ kan oṣelu ninu ni. Ko sẹni to mọ ibi ti Tinubu n lọ ti oju fi n kan an bẹẹ, afi nigba to de ọdọ Baba Ayọ Adebanjọ, aṣaaju awọn Afẹnifẹre, to si n fi ohun oke sọ fun baba naa pe, “Mi o le duro pẹ! Mo n lọ si Kano! Kano la n lọ!” Bi Tinubu ti ṣe jade nibi isinku Ibadan yii niyẹn.
Ni tootọ, nigba ti yoo fi to wakati meji ti Aṣiwaju APC yii sọrọ yii, awọn ara Kano ti ri i. Ṣe ẹronpileeni adani tirẹ lo gbe lọ, olowo kuku ṣe ohun gbogbo tan, ọmọ talaka nikan ni yoo ni iṣoro. Ki i ṣe pe Tinubu deede balẹ si Kano, Gomina ipinlẹ naa ti n duro de e, iyẹn Abdullahi Ganduje, nigba to si foju kan Tinubu, niṣe lo dirọ mọ ọn, lẹyin naa lo ki Baba Akande ati Nuhu Ribadu ti wọn jọ lọ. Ganduje ti gbe bọọsi kan kalẹ, bọọsi naa ni gbogbo wọn si ko si, oun naa lo si gbe wọn lọ si ibi ayẹyẹ ti wọn tori ẹ wa gan-an. Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ju ni ibi ayẹyẹ ti Tinubu lọ, wọn ti ro pe ayẹyẹ kan ti yoo ni ọpọlọpọ ero nibẹ ni, ayẹyẹ ti awọn alagbara Naijiria yoo peju pesẹ si. Ṣugbọn ko ri bẹẹ, awọn alejo pataki to wa nibẹ naa ni Tinubu, Akande ati Ribadu, koda Ganduje paapaa ko mọ si i, nitori Tinubu lo ṣe lọ.
Ọkunrin Aafa kan, Shehu Muhammad Bin Uthman, lo n sin ọmọ rẹ re ile ọkọ, ode awọn alaafaa ni, awọn naa ni wọn si pọ ju nibẹ. Tinubu funra ẹ sọ ọ, o ni bo tilẹ jẹ pe ayẹyẹ igbeyawo naa ku ọla ni oun gba iwe ipe wọn, oun pinnu lati wa nitori oun mọ pe ohun to da lori iṣọkan Naijiria ni, oun si ranṣẹ si Ganduje pe oun n bọ ni Kano o, boya o wa nile tabi ko si nile, oun n bọ ni toun. Ganduje naa sọrọ, o ni nigba ti oun gbọ pe Tinubu n bọ ni Kano, oun wa lẹyin odi ipinlẹ naa, kia loun pa gbogbo ohun ti oun n ṣe ti, oun ni Tinubu gbọdọ ba oun nile, oun ko si ni i ṣe ohunkohun, tabi lọ sibikibi, titi ti Tinubu yoo fi de. Ki i ṣe wiwa ti Tinubu wa sibi igbeyawo naa ati ọrọ to sọ nipa iṣọkan Naijiria nibẹ lo ṣe pataki, bi ko ṣe ohun to ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ti ṣe ayẹyẹ iyawo naa tan. Ohun to si ṣẹlẹ yii lo fi han pe ohun to wa lẹyin ọfa ju oje lọ, irin-ajo naa ki i ṣe tigbeyawo, ti oṣelu pọnnbele ni.
Ohun ti Tinubu ṣe ni gbara ti wọn ṣegbeyawo yii tan ni lati maa kiri ile awọn agbaagba Musulumi, awọn olori ẹlẹsin ati awọn olori aafaa gbogbo nibẹ, o si n ri wọn, o n ba wọn nile, ti gbogbo wọn si n ṣe e lalejo daadaa. Nigbẹyin, awọn aafaa gbogbo ni Kano, awọn olori ijọ gbogbo, pe jọ ni mọṣalaṣi nla Alfurqan, nibi ti Tinubu ti lọọ ba gbogbo wọn sọrọ, to si sọ fun wọn pe ki wọn ma jẹ ki awọn gba fun awọn kan ti wọn fẹẹ pin Naijiria si wẹwẹ, pe bi awọn ba ti wa niṣọkan, awọn ti wọn n mura lati fọ Naijiria si yẹlẹyẹlẹ yii, ko ni i ṣee ṣe fun wọn. Nibẹ lawọn olori ijọba yii ti bẹrẹ si i sọrọ, kia lọrọ naa si ti kuro ni ti ọrọ ẹsin, o di ti oṣelu pata. Olori awọn ijọ Sunnah sọ pe ojulowo ọmọ Naijiria ni Tinubu, oun yoo si wa lẹyin ẹ lati du ipo aarẹ. O ni gbogbo awọn Musulumi ilẹ Hausa ni yoo duro ti i, ko si sewu kan fun un, nitori asiko niyi lati san ẹsan oore to ṣe fọmọ awọn, Buhari, ni 2015.
Olori ijọ Tijaniyaa ni Kano, Ibrahim Shehu Mai JHula, ni nigba ti oju ogun le, Tinubu lawọn ri to duro ti Buhari ni gbogbo ilẹ Yoruba, oun lo si ṣe okunfa bi awọn Yoruba gbogbo ṣe ṣe atilẹyin fun un. O ni ko si ara ilẹ Hausa kan ti yoo gbagbe ohun ti aṣiwaju APC naa ṣe, asiko si ti to ti oun naa yoo kore ohun to ṣe. Bẹẹ ni aṣoju awọn ijọ Kahjdiriya naa ni, gbogbo ohun ti Tinubu ba fẹ ni Ọlọrun yoo ṣe fun un, paapaa ni ti ọrọ ipo to fẹẹ du ni Naijiria. Lọrọ kan, awọn olori ẹlẹsin ni Kano ti ni ki Tinubu maa niṣo, awọn yoo wa lẹyin rẹ lati de gbogbo ibi to ba fẹẹ lọ. Nigba yii ni awọn eeyan mọ ohun to gbe Tinubu lọ si Kano gan-an, o si ye gbogbo ẹni ti ko ba mọ tẹlẹ pe ọrọ oṣelu ti bẹrẹ loju mejeeji loootọ, Tinubu ko si fi bo mọ pe oun yoo du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023, iṣẹ naa si ti bẹrẹ pẹrẹwu.
Ṣugbọn bi nnkan ti n lọ yii, ologbo ti yoo pa aguntan jẹ laarin oru ni o, gbogbo awọn ti wọn ti sun ni wọn yoo ji silẹ, nigba ti ọrọ naa yoo ba di ariwo rẹpẹtẹ. Tinubu nikan kọ lo fẹẹ dupo aarẹ. Tunde Bakare wa nibẹ to ni Ọlọrun ti fi han oun pe oun loun yoo gba ijọba lọwọ Buhari yii, bi Buhari atawọn eeyan rẹ si ti n ṣe si i jọ pe ọrọ naa le ṣẹ. Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo naa ko duro rara mọ, o ti sọ ara rẹ di ologbo to sun bii ọlẹ, afaimọ ko ma ko ẹran jẹ bi ile ba da. Awọn kan wa ti wọn ni ti Ọṣinbajo lawọn fẹ, wọn ni o ti mọ ọwọ Buhari latigba ti wọn ti n ṣejọba yii, o si daju pe yoo maa ba awọn eto wọn ti wọn gbe kalẹ lọ ni. Bẹẹ naa ni Gomina Kayọde Fayẹmi ti Ekiti, oun naa ti ba iṣẹ jinna lori ọrọ ipo aarẹ 2023 yii. Ṣugbọn iṣoro kan wa fun gbogbo awọn ti wọn n mura lati du ipo aarẹ yii, iṣoro naa ti di wahala fun wọn, o si ti dija rẹpẹtẹ laarin awọn APC nile-loko.
Gbogbo awọn ti wọn n du ipo yii, ati awọn mi-in ti wọn ko ti i jade lati ilẹ Ibo, ohun ti wọn ti ro lọkan wọn tẹlẹ ni pe niwọn igba to jẹ Buhari to ṣejọba yii, lati ilẹ Hausa lo ti wa, ẹni yoowu ti yoo ba gba ipo aarẹ lẹyin ẹ, ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo ni tọhun gbọdọ ti wa. Adehun to wa laarin wọn niyi. Loootọ ki i ṣe pe wọn kọ adehun yii silẹ, tabi sinu iwe ofin ẹgbẹ APC, ṣugbọn kaluku wọn lo mọ lọkan ara wọn pe lẹyin ti Buhari ba jẹ tan, ara Guusu Naijiria, ni ipo naa yoo kan. Ati pe nitori atilẹyin ti Yoruba ṣe fun Buhari, ko si ẹni meji to yẹ ko ba a du ipo naa, wọn ti ro pe Tinubu ni ipo naa yoo tọ si. Eyi yoo si rọrun fun un to ba jẹ ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo ni awọn eeyan ti jade lati du ipo aarẹ, nitori wọn ti mọ pe ko sẹni to le na ọkunrin naa, tabi ti yoo fẹyin rẹ janlẹ ninu awọn yoowu to ba jade, oun ni yoo bori wọn.
Ṣugbọn nibi ti awọn ti fọkan balẹ pe bi ọrọ yoo ti ri niyi ni wahala ti de. Ede-aiyede de ninu APC, ija si bẹ lojiji. Ohun to fa ija yii ni pe awọn ọmọ Buhari kan ti ko ara wọn jọ, wọn ni ko si adehun kan laarin awọn tabi nibikibi to ni ki awọn Hausa ma du ipo aarẹ ni 2023, ko tilẹ sohun to jọ bẹẹ ninu APC, awọn ọmọ Hausa yoo du ipo naa daadaa, bo ba si ja mọ wọn lọwọ, a jẹ pe bi Ọlọrun ti fẹ ẹ niyi, awọn naa lawọn yoo maa ṣejọba lẹyin ti Buhari ba ti lọ. Ohun to n bi awọn ọmọ Tinubu ninu ree, ti wọn si n mu kinni naa mọra lati ọjọ yii wa, ti wọn ko fẹẹ da nnkan ru. Ṣugbọn laarin ọsẹ meji to kọja yii, ohun meji pataki ṣẹlẹ to fi han pe oku ti APC sin, ẹsẹ rẹ n fẹẹ yọ sita wayi, ija buruku kan yoo ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa ko too di 2023 ti wọn yoo dibo yii, bi wọn ko si ṣọra ṣe, ija naa le fọ ẹgbẹ yii patapata. Awọn ọmọ Tinubu ni wọn yari!