Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Deji tilu Akurẹ, Ọba Aladeyoyinbo Aladelusi, ti pe ijọba ipinlẹ Ondo lẹjọ lori ọrọ Ọba Aralepo ti Isikan ti wọn ṣẹṣẹ fi jẹ laipẹ yii.
Lati bii ọsẹ kan sẹyin ni awuyewuye ti n waye lori ẹni to yẹ ki wọn fi jẹ oye Aralepo Isikan to jẹ agbegbe kan laarin igboro Akurẹ.
Bi Deji ṣe kede yiyan Ọmọọba Adeyẹye Henry Gbenga gẹgẹ bii ọba tuntun lawọn ijoye kan n’Isikan naa tun ko ara wọn jọ lati dibo yan ẹlomin-in, iyẹn Ọmọọba Olugbenga Ojo.
Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji ni wọn ṣi n leri pe awọn gan-an loye ọhun tọ si, sibẹ, o da bii pe awọn ilu ati ijọba fẹẹ fara mọ Ọmọọba Ojo tawọn eeyan ilu naa dibo yan ju ẹni ti Deji fẹẹ fa kalẹ lọ.
Gbogbo eyi ni Ọba Aladetoyinbo atawọn Oloye giga Akurẹ ro papọ ti wọn fi gbe Gomina Rotimi Akeredolu, Kọmiṣanna feto idajọ, Amofin Charles Titiloye, atawọn mẹfa mi-in lọ sile-ẹjọ.
Ẹbẹ Deji ni pe kile-ẹjọ ka awọn olujẹjọ naa lọwọ ko lati ma ṣe lọwọ ninu fífi ẹnikẹni joye Iralepo Isikan niwọn igba ti ẹjọ kan si n lọ lọwọ nile-ẹjọ lori rẹ.
Igbẹjọ yii la gbọ pe yoo maa tẹsiwaju lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla, ọdun ta a wa yii.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ ọhun, Aralepo ti wọn dibo yan, Ọmọọba Oluwagbenga Ojo, juwe ẹjọ ti wọn pe naa bii eyi ti ko lẹsẹ nilẹ nitori pe afọju ati aditi gan-an mọ pe wọn ti fọba tuntun jẹ gẹgẹ bii Isikan.
O ni awọn Uharẹfa lo dibo to gbe oun de ipo gẹgẹ bii ọba, ni ibamu pẹlu aṣa ati iṣe ilu Isikan, ti awọn aṣoju lati ijọba ibilẹ Guusu Akurẹ si wa nikalẹ lati bojuto eto naa.
O ni ofo ọjọ keji ọja ni ẹjọ ti Deji atawọn oloye rẹ ṣẹṣẹ n pe lẹyin tawọn Uharẹfa ti pari gbogbo etutu to yẹ ki wọn ṣe fun ọba tuntun to gori oye, ti ọba naa si ti ko wọ aafin lati bẹrẹ ojuṣe rẹ lori ilu to jọba le lori.