Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Asiko ta a wa yii kii ṣeyi to rọrun rara fun oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto didbo to n bọ yii, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, mọ pẹlu bawọn agba oloṣelu ti wọn jọ dije ninu eto idibo abẹle to kọja ṣe n pada lẹyin rẹ lọkọọkan, ti wọn si n darapọ mọ ẹgbẹ mi-in.
Pupọ awọn oludije ọhun ni inu wọn kọkọ dun lẹyin ti wọn kede Jẹgẹdẹ pe oun lo jawe olubori ninu eto idibo naa, gbogbo wọn ni wọn si jọ gba pe awọn yoo ṣiṣẹ pọ ki ọkunrin agbẹjọro agba naa le rọwọ mu ninu eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, osu to n bọ.
Ohun tawọn eeyan n reti ni kete ti Agboọla Ajayi ti kẹru rẹ kuro ninu ẹgbẹ PDP ni pe ọkan ninu awọn ti wọn jọ dije ni Jẹgẹdẹ yoo mu gẹgẹ bii igbakeji rẹ, ṣugbọn ọrọ pada yipada pẹlu bi ọkunrin naa ṣe kede orukọ aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Irele ati Oktipupa nile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnarebu Ikengboju Gboluga.
Lati igba naa ni nnkan ko ti fi bẹẹ lọ deede mọ laarin wọn. Ọkunrin agbẹjọro yii nikan lawọn eeyan si n ri to n funra rẹ polongo ibo kaakiri ipinlẹ Ondo, ko sẹni teeyan tun le sọ pe o fi gbogbo ara ba a ṣiṣẹ pọ gẹgẹ bii ipinnu ti wọn kọkọ ṣe.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ọkan ninu awọn oludije naa, Ọgbẹni Banji Okunọmọ, binu kuro ninu ẹgbẹ PDP, to si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ ZLP.
Okunọmọ to ti figba kan jẹ akọwe ipongo fun ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo lorukọ rẹ wa lara awọn ti Jẹgẹdẹ kọkọ fi ṣọwọ si awọn asaaju ẹgbẹ wọn l’Abuja gẹgẹ bii igbakeji rẹ.
Ohun to ṣokunfa bi ajọ eleto idibo ṣe waa kede orukọ mi-in to yatọ lo ṣi n ya awọn eeyan lẹnu. Ọrọ yii naa ni wọn lo ṣi n da wahala abẹnu sile, eyi ti wọn ko ti i ri yanju laarin awọn oludije naa.