Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Yoo pẹ gan-an ki igbimọ to n gbọ ifisun lori ifiyajẹni awọn ọlọpaa SARS nipinlẹ Ogun too sinmi. Idi ni pe ojumọ kan, ifisun kan ni. Bo si ti wu ki iṣẹlẹ pẹ to, awọn to ṣẹlẹ si n waa ṣalaye ẹ gẹgẹ bijọba ṣe fun wọn ni anfaani bayii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọmọkunrin kan to ti fẹrẹ pari ẹkọ ẹ ni yunifasiti ijọba to wa ni Abẹokuta ti wọn tun n pe ni FUNNAB, Ṣeyi Akinade, mu majele ti wọn n pe ni Sniper lọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, o si ku.
Ohun to fa a ni pe o padanu miliọnu meje naira ninu okoowo ayelujara to n ṣe.
Awọn ọlọpaa kan ti wọn n pe ni Zonal Intervention Squard, to jẹ eka SARS, l’Ọbada-Oko, ni wọn ya bo ile awọn akẹkọọ yii lọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun 2020, ti wọn ni awọn gbọ pe wọn n mugbo, wọn si n ṣe ‘Yahoo’ nibẹ.
Ṣeyi Akiande wa lara awọn ti wọn ko lọ si teṣan wọn lalẹ ọjọ naa, wọn si ni wọn ti wọn mọ inu sẹẹli pẹlu awọn ọdaran, wọn gba foonu lọwọ wọn, wọn si ni afi ki wọn san miliọnu meji naira fun beeli.
Oloogbe Akinade sọ fawọn ọlọpaa naa pe bisinẹẹsi kan wa toun ti ṣi kalẹ lori ẹka kan lori ayelujara, boun ko ba fi le debẹ kilẹ too mọ, miliọnu meje loun yoo padanu, oun ko si fẹ ki eyi waye, nitori naa, ki wọn foun ni foonu ati kọmputa oun ti wọn gba, koun le fi pari okoowo naa, lẹyin naa, oun yoo ṣe ohun ti wọn ba fẹ.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa naa ko fun Ṣeyi lohun to beere, o si ṣe bẹẹ padanu owo ọhun, bẹẹ ni wọn ko ṣi i silẹ ninu igbekun to wa.
Ọrẹ oloogbe yii kan to waa jẹrii gbe e ni kootu Majisireeti Iṣabọ ti ẹjọ naa ti waye l’Ọjọbọ to kọja, iyẹn Damilare Adejọrọ, ti wọn jọ mu wọn, ṣalaye fun igbimọ naa pe ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira (120,000) lawọn ZIS gba lọwọ awọn ki wọn too fi awọn silẹ, bẹẹ, wọn ko sọ pato ẹṣẹ tawọn ṣẹ.
O ni latigba ti ọrẹ oun ti de latọdọ awọn ọlọpaa naa lo ti bẹrẹ si i ronu, ti ko fi ọkan si ohunkohun mọ, ti ko si ki i ba awọn eeyan ṣe bo ṣe n ṣe tẹlẹ mọ.
Ko too di ọjọ kejilelogun to mu Sniper, Ṣeyi Akiande bọ sori ikanni Fesibuuku rẹ, o si kọ ọ sibẹ pe, ‘‘Mo lero pe o ti tan bayii, o dabọ. Ko sẹni to gbọ igbe mi nigba ti mo n sunkun pe ki wọn gba mi, ki wọn gba ẹtọ mi fun mi. O di dandan ki eyi ṣẹlẹ. Ile aye, o dabọ’
Lasiko ti Ṣeyi n kọ ọrọ naa sori ayelujara, o ti mu majele. Nigba tawọn eeyan yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọmọkunrin ti wọn ni olowo ni laarin awọn ẹgbẹ ẹ naa ti dagbere faye.
Nigba ti anfaani waa ṣi silẹ bayii lati sọ ẹdun ọkan ẹni, Iya Ṣeyi, Abilekọ Funmilayọ Akinade, wa siwaju igbimọ olugbẹjọ naa, o ni ki wọn gba ọrọ oun yẹwo, nitori SARS lo jẹ kọmọ oun padanu owo to tori ẹ para ẹ.
Iya Ṣeyi sọ pe bi SARS ko ba mu un laiṣẹ, ti wọn ko ti i mọle fun ọpọlọpọ ọjọ lai ṣe nnkan kan, ọmọ oun ko ni i bẹrẹ ironu, debi ti yoo fi gbe majele jẹ.
Iya naa rọ ijọba pe ki wọn ma jẹ kọmọ oun ku gbe, ki wọn ba oun da sẹria fawọn ọlọpaa to kan oun leyin ọọkan ni.
Ọkan ninu awọn ọlọpaa ti wọn waa ko awọn akẹkọọ naa lọjọ ọhun, Inspẹkitọ Babajide Adebusuyi, wa ni kootu lọjọ yii. Ohun to sọ ni pe loootọ lawọn mu Ṣeyi atawọn yooku ẹ, ohun tawọn si mu wọn fun ni igbo tawọn gbọ pe wọn n mu ninu ile wọn to wa lagbegbe Camp, l’Abẹokuta.
Adebusuyi sọ pe bo tilẹ jẹ pe oloogbe yii atawọn ọrẹ ẹ ko si ninu awọn to n mugbo, o di dandan kawọn ko wọn pọ, nigba to jẹ gbogbo wọn lawọn ba nibẹ lọjọ naa.