Nitori ifẹhonu han to n lọ lọwọ lori SARS, ijọba ipinlẹ Eko ti pasẹ pe ki wọn ti gbogbo awọn ileewe aladaani ati tijọba to wa nipinlẹ naa pa.
Kọmiṣṣana feto ẹkọ nipinlẹ Eko, Arabinrin Fọlaṣade Adefisayọ, to kede ọrọ yii sọ pe aabo awọn akẹkọọ, olukọ, awọn obi atawọn to n ṣiṣẹ ni awọn ileewe naa ṣe pataki ni asiko ti o lagbara ti a wa yii.
O waa rọ awọn ileewe wọnyi lati ṣamulo awọn ọna ikẹkọọ mi-in bii redio, tẹlifiṣan, ẹkọ kikọ lori ẹrọ agbọrọkaye atawọn ilana mi-in tawọn ileewe ti n lo lasiko ti arun korona wa nita.
Adefisayọ ni ijọba yoo kede ọjọ iwọle mi-in fawọn ileewe laipe jọjọ, iyẹn ti ohun gbogbo ba ti bọ sipo.