Nitori iwọde to n bọ,  ọga ọlọpaa ni ki wọn maa ko aloku taya kaakiri ṣọọbu awọn fọganaisa

Adewale adeoye

Pẹlu bi ọjọ tawọn araalu lawọn fẹẹ ṣewọde ita gbangba ṣe n sun mọ etile bayii, ọga agba ọlọpaa patapata lorileede wa, Kayọde Ẹgbẹtokun, ti paṣẹ fawọn kọmiṣanna ọlọpaa ni gbogbo ipinlẹ lorileede yii pe ki wọn ri i daju pe awọn araalu ti wọn fẹẹ ṣewọde ita gbangba naa ko ri taya mọto lati jo nina loju titi, ati nibi gbogbo to ṣe pataki laarin ilu lorileede yii rara.

Lara ọna ti wọn ni ki wọn gba ni pe ki awọn ọlọpaa nipinlẹ kọọkan lọ sawọn igberiko atawọn abule, ki wọn lọọ ko awọn taya aloku mọto kuro lọdọ awọn fọganaisa gbogbo, kawọn araalu ti wọn fẹẹ ṣewọde naa ma baa le ri aloku taya mọto lati lo rara.

Awo ọrọ ọhun lu sita lati ọdọ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, lasiko to n jabọ aṣẹ ati ikilọ ti Egbẹtokun fun wọn nipinlẹ gbogbo. Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Adeniran Akinwale, sọ fawọn ọga ọlọpaa iyẹn (DPO) gbogbo ti wọn wa labẹ rẹ kaakiri teṣan wọn nipinlẹ Ekiti pe ki wọn ri i daju pe wọn lọ kaakiri aarin ilu, paapaa ju lọ, awọn igberiko, lati lọọ ko gbogbo aloku taya mọto to ba wa lọdọ awọn fọganaisa, kawọn araalu, atawọn ọdọ ma le ri ohun ti wọn maa lo lati fi dana loju titi lasiko ti wọn ba n ṣewọde ifẹhonu han wọn yii.

O ni ki wọn lọọ ko awọn aloku taya mọto naa ni ṣọọbu awọn fọganaisa yii loru. Ati pe ọga ọlọpaa teṣan yoowu to ba laju rẹ silẹ lasiko iwọde ifẹhonu han naa tawọn eeyan agbegbe rẹ ba jo taya mọto loju titi, rọhun yoo jiyan rẹ niṣu.

Ṣugbọn ọkunrin yii ko ṣalaye irufẹ ijiya to wa fun irufẹ ọga ọlọpaa bẹẹ  lasiko to n ba awọn ọmọọṣẹ rẹ  sọrọ.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni awọn araalu lawọn maa ṣewọde ita gbangba lati fẹhonu wọn lori bi nnkan ṣe ri lorileede yii. Bi eounjẹ ṣe wọn, ti epo bẹntiroolu naa gbowo lori, ti ọrọ aje gbogbo s dẹnu kọlẹ.

Leave a Reply