Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
O ti le loṣu kan bayii ti awọn ile-ẹjọ nipinlẹ Ogun ti n yanṣẹ lodi, to jẹ ko si kootu to jokoo gbọ ẹjọ mọ, nitori wọn ni ijọba ko sanwo oṣu awọn bo ṣe yẹ ki wọn san an, idaji owo ni wọn n san.
Iyanṣẹlodi naa lo waa fa a ti awọn sẹẹli ọlọpaa ti wọn n fi awọn afurasi ọdaran pamọ si fi n kun akunfaya bayii nipinlẹ yii, nitori ko si kootu ti wọn yoo gbe wọn lọ fun igbẹjọ ati idajọ.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi eyi mulẹ. O ni awọn ki i ti awọn ti ẹṣẹ wọn ko ba fi bẹẹ lagbara mọle mọ bayii, awọn n fun wọn ni beeli lẹsẹkẹsẹ ni.
Oyeyẹmi ṣalaye pe idi ni pe awọn aaye tawọn n tọju afurasi si ti kun, bẹẹ awọn ẹṣẹ kan wa to jẹ ko ṣee gba beeli rẹ, afi kẹni to ba daran naa foju ba ile-ẹjọ, ki wọn dajọ rẹ sibi ti yẹ ko ti lọọ jiya ẹṣẹ.
Awọn ẹsun bii ipaniyan, ijinigbe, idigunjale atawọn mi-in to fara pẹ ẹ ko ṣee de mọ sẹẹli gẹgẹ bi Alukoro ṣe wi, o ni afi kawọn ti wọn mọle, kawọn gbe wọn lọ si kootu, ki kootu si dajọ wọn.
O ni ṣugbọn lati oṣu kan sẹyin ti kootu ko ti ṣiṣẹ, ti awọn ẹsun bayii si n ṣẹlẹ, ko sibi tawọn yoo gbe awọn afurasi naa lọ fun igbẹjọ, eyi to fa a tawọn fi n ti wọn mọ sẹẹli, ti aaye naa ko si yee kun si i nitori awọn oniṣẹ ibi ti wọn ko yee huwa to ta ko ofin.
Yatọ si tawọn ọlọpaa, oṣiṣẹ kootu Ake kan to ba wa sọrọ ṣalaye pe iyanṣẹlodi yii n pa awọn lara pupọ, nitori atijẹ-atimu ko dẹrun rara.
O ni ki i ṣe pe o wu awọn naa lati maa yanṣẹlodi, ṣugbọn nigba to jẹ idaji owo-oṣu nijọba n san fawọn, to tun jẹ wọn ko yee yọ owo kọpuretiifu lara awọn loṣoosu, bẹẹ, wọn ko sanwo naa fawọn.
Akọwe kootu to ni ka ma darukọ oun yii sọ pe ọdun 2019 loun ti gba ajẹmọnu owo kọpuretiifu yii gbẹyin, o lo ti di oṣu mejidinlogun bayii tijọba jẹ awọn ti wọn ko san.
Ṣa, o lawọn yoo maa ba iyanṣẹlodi naa lọ ni o, afi tijọba ipinlẹ Ogun ba da awọn lohun lawọn yoo too pada sẹnu iṣẹ.
Awọn lọọya naa to jẹ kootu ni ibudo ounjẹ wọn, awọn naa ṣalaye pe nnkan ko dẹrun, nitori awọn ko rẹjọ ṣe ni kootu mọ, nigba tile-ẹjọ kọ ti wọn ko ṣilẹkun.