Monisọla Saka
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa, ti paṣẹ pe ki wọn yọ DPO, ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Ọlọsan, ni Mushin, ipinlẹ Eko, nipo, lẹyẹ-o-sọka, nitori awọn iwa aitọ kan to ṣẹlẹ ni teṣan rẹ.
Bẹẹ lo tun pa a laṣẹ pe ki wọn fofin de awọn lọgaalọgaa ọlọpaa teṣan ọhun, ti wọn fẹsun kan pe wọn huwa aidaa si obinrin kan to n pe fun idajọ ododo, nitori nnkan ti wọn ṣe fun un.
Ninu ọrọ ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, kọ sori ikanni abẹyẹfo, iyẹn Twitter rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lo ti ṣalaye pe, Owohunwa ti paṣẹ pe ki wọn gbe igbesẹ, lẹyin to gbọrọ lẹnu ọtun atosi.
“Nitori bi ọrọ ẹjọ yii ṣe ka ọga lara, ati lati ri i daju pe idajọ ododo waye, funra CP Idowu Owohunwa, lo fọrọ wa awọn eeyan tọrọ kan, to fi mọ awọn olugbe, onile atawọn alaga kansu ti wọn n ṣoju agbegbe naa, lẹnu wo.
Bẹẹ ni lọọya to n ṣoju ileeṣẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan, awọn mọlẹbi Ọmọlara, Bebex atawọn oṣiṣẹ abẹ ẹ, atawọn agbẹjọro awọn mejeeji yii ni wọn wa nikalẹ.
Nnkan idunnu ati iwuri ni pe a ti ni ọrọ to duroore, fun idi eyi, a ti ni ẹjọ to lẹsẹ nilẹ, ta a le gbe siwaju ile-ẹjọ.
“Lẹyin ti CP Owohunwa ti gbọ ẹjọ ẹnu ẹni kin-in-ni ati ikeji tan, lo ti sọ pe lai si ani-ani, ẹjọ n bẹ lati gbe dewaju adajọ ninu ọrọ yii, nitori bẹẹ lo si ṣe paṣẹ pe ki wọn maa taari ẹjọ naa lọ si kootu ni kiakia”.
Hundenyin ni kọmiṣanna tọka sawọn kudiẹ-kudiẹ kan ninu nnkan tawọn ọga ọlọpaa tọrọ kan naa ṣe. O ni nitori bẹẹ lọga awọn ṣe paṣẹ pe ki wọn gbe igbesẹ lori bi wọn yoo ṣe fiya to tọ jẹ awọn agbofinro naa.
Fun idi eyi, wọn ti paṣẹ pe ki awọn ọga ọlọpaa wọnyi, latori DPO tẹsan Ọlọsan, ni Muṣin, ati gbogbo awọn ọga ọlọpaa ti wọn darukọ yii, ti wọn ṣe aṣemaṣe lakata ẹ, ṣi fi ipo ti wọn wa silẹ na, ki wọn lọọ rọọkun nile, lẹyẹ-o-sọka.
Ohun ti wọn lo ṣẹlẹ ni pe wọn fọ olufisun to jẹ iyawo ile kan leti, nitori ko gba lati maa ba ọkunrin kan ti wọn n pe ni Bebex, lagbegbe Ladipọ, Mushin, nipinlẹ Eko, dọrẹẹ.
Obinrin naa si sare fi foonu rẹ ka fidio iṣẹlẹ naa silẹ, nibẹ lo ti n ke pe awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan, lati jọọ waa ja foun lati gba idajọ ododo, nitori Bebex toun ba lọrọ yii lowo, o si tun lẹnu lawujọ. Fọnran fidio yii lo ju sori ẹrọ ayelujara, tọrọ naa fi de ọdọ Kọmiṣanna ọlọpaa.
Nigba ti wọn ko ẹjọ naa lọ si agọ ọlọpaa Mushin yii, niṣe lawọn ọlọpaa to wa ni teṣan naa n ṣe obinrin naa baṣu-baṣu, ti wọn n fiya jẹ ẹ, lẹyin naa ni wọn fipa mu un, lati ṣe fidio mi-in, ti wọn ni yi ọrọ ẹnu ẹ pada, pe irọ loun n pa ninu fidio akọkọ toun ṣe.
Ṣa, kọmiṣanna ọlọpaa ti ni ki wọn maa ko ẹjọ naa lọ siwaju adajọ kootu.