Nitori iyawo mi ni mo ṣe ji ọkada ti Amọtẹkun ka mọ mi lọwọ – Abdullahi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Rasheed Abdullahi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, lọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun ole jija.

Nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe mu un, Alakoso ajọ naa, Dokita Ọmọyẹle Adekunle, ni ilu Omu-Aran, nipinlẹ Kwara, ni Abdullahi ti ji ọkada naa, o si gbe e wa siluu Ila Ọrangun, nipinlẹ Ọṣun, nibi t’ọwọ ti tẹ ẹ laago mẹta ọsan ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Ọmọyẹle ṣalaye pe lasiko ti ọkunrin naa n gbe ọkada Bajaj ti ko ni nọmba ọhun kaakiri lawọn Amọtẹkun da a duro, ti ko si le ṣalaye ibi to ti ri i fun wọn.

Lẹyin ti wọn tẹ ẹ ninu daadaa lo jẹwọ pe ṣe loun ji ọkada naa, ati pe bi oun ṣe ji i loun ti ko ẹru oun kuro niluu Omu-Aran, toun si sa wa si Ila-Ọrangun.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Abdullahi sọ pe ara iyawo oun ti ko ya loun fẹẹ fi owo ọkada naa tọju, idi si niyẹn ti oun fi ji i.

O ni ṣe loun ṣọ ẹni to ni ọkada naa lasiko tiyẹn fẹẹ lọọ kirun ninu mọṣalaaṣi, ati pe bo ṣe wọ’bẹ loun ji ọkada naa gbe, ti oun si mori le ilu Ila-Ọrangun.

Ọmọyẹle waa fi da awọn araalu loju pe ipinlẹ Ọṣun ko ni i gba awọn ọbayejẹ, o ni ẹni to ni ọkada naa ti yọju, bẹẹ lawọn yoo taari Abdullahi sọdọ awọn agbofinro ipinlẹ Kwara lati tẹsiwaju ninu iwadii wọn.

Leave a Reply