Nitori ki eto aabo le gbopọn si i, awọn araalu ro fijilante lagbara ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lati fopin si iwa ijinigbe lawọn ijọba ibilẹ kan ni Guusu ipinlẹ Kwara, lo mu ki awọn olugbe Àrán-Ọ̀rin, nijọba ibilẹ Ìrẹ́pọ̀dùn, da owo jọ, ti wọn si ra ọkada meji, eyi ti wọn ko fun ẹgbẹ fijilante agbegbe naa lati gbogun ti iwa ọdaran, ati ki gbogbo agbegbe naa le wa ni alaafia. Bakan naa ni wọn fun wọn lowo ki iṣẹ wọn le rọrun ni ṣiṣe.

Nigba to n ṣọrọ lojude ọba ilu naa, Aarẹ ẹgbẹ idagbasoke ọmọ bibi ilu Àrán-Ọ̀rin, Architect Julius Babalọla, ni awọn gbe igbeṣẹ yii lati ro awọn fijilante lagbara lati mu iṣẹ rọrun fun wọn ni ṣiṣe, ati lati gbogun ti ajinigbe ti wọn n yọ awọn agbegbe wọn lẹnu.

O tẹsiwaju pe loootọ ki i ṣe pe awọn ajinigbe yii n fi bẹẹ yọ awọn lẹnu, ṣugbọn gbogbo awọn ilu to yi awọn ka ni awọn ajinigbe naa ti n ṣoro. Owe Yoruba lo si ni iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni.

O ni, “A n gbọ pe awọn ajinigbe n yọ awọn araalu lẹnu lawọn ilu to yi wa ka. Lati dena iru ohun buruku bayii niluu Àrán-Ọ̀rin, a ni lati ro awọn fijilante wa lagbara, ki wọn le lagbara si i, ki wọn si maa daabo bo gbogbo araalu”.

O rọ gbogbo araalu ki wọn maa ṣọrọ soke nigbakuugba ti wọn ba kẹẹfin irin-ajoji tabi ẹni ti iṣẹ ọwọ rẹ ko mọ lagbegbe wọn.

Bakan naa lo lu awọn araalu lọgọ ẹnu pẹlu bi wọn ṣe dawo jọ, ti wọn si peṣe ina sola ṣaarin ilu, ki gbogbo rẹ le mọlẹ kedere, o ni eyi yoo tun mu ki aabo wa ninu ilu naa.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni ẹgbẹ awọn ti pa itu meje tawọn ọdẹ maa n pa ninu igbo lati ri i pe idagbasoke ti ko lẹgbẹ ba ilu awọn. O fi kun un pe awọn tun ṣe atunṣe awọn kanga-dẹrọ tijọba ṣe fun ilu ti wọn ti bajẹ, o ni gbogbo ẹ pata ni awọn tunṣe, ti wọn si ti n ṣiṣẹ bayii.

 

Leave a Reply