Nitori ki n le baa fun ọkọ mi lọmu mu ni mo ṣe fẹẹ bimọ kẹrin

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọrọ iyaale ile kan, Abilekọ Rachel Bailey, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, to n gbe ni Florida, lorileede Amẹrika, ṣi n ya ọpọ eeyan lẹnu. Ko sohun meji to jẹ kọrọ rẹ jẹ iyalẹnu ju pe aipẹ yii lo kede pe oun maa too loyun nigba kẹrin lati le maa fun ọkọ oun lọmu mu gẹgẹ bii iṣe awọn ninu ile.

Ọkọ iyaale ile naa, Ọgbẹni Alexander, ẹni ọgbọn ọdun, lo jẹ pe o kundun lati maa mu ọmu iyawo rẹ lasiko tiyawo rẹ ba n tọmọ lọwọ, ọpọ igba lo jẹ pe ṣe loun ati ọmọ tiyawo rẹ ba n tọ lọwọ maa n jijada ọmu ni.

ALAROYE gbọ pe ọmọ mẹta akọkọ tawọn tọkọ-taya yii bi ti janu kuro lọmu, ṣugbọn Bailey ṣi nifẹẹ si i pupọ lati maa fun ọkọ rẹ lọmu mu lalaalẹ gẹgẹ bo ṣe n ṣe nigba to n tọmọ lọwọ, eyi, atawọn idi mi-in lo ro papọ to fi kede rẹ lọsẹ yii pe oun maa too bimọ kẹrin laipẹ yii, koun baa le maa fun ọkọ oun lọmu mu lalaalẹ nigba gbogbo.

Ọdun 2016 ni aṣa ọhun kọkọ bẹrẹ laarin tọkọ-taya naa nigba ti Bailey lọọ gbafẹ lori omi pẹlu awọn ọrẹ rẹ, o gbe ọmọ to n tọ lọwọ silẹ nile, loun pẹlu ọkọ rẹ ba gba ori omi lọ. Ko ranti lati mu ohun eelo to ma fi n fa omi ọmu rẹ kuro lasiko ti ọmu ba n ro o lọwọ dani, ko pẹ rara ti ọmu rẹ fi kun gidi, ara bẹrẹ si i ro o, n lọkọ rẹ ba ran an lọwọ lati ba a fẹnu fa omi ọmu rẹ jade, kaka ki ọkọ tu omi naa danu, ṣe lo gbe e mu, latigba naa lo si ti n mu ọmu iyawo rẹ. Bẹẹ niyawo paapaa ko fiya ọmu naa jẹ ẹ rara, lo ba di pe ọkọ ati ọmọ ti Bailey n tọ ni wọn jọ n ja si ọmu, aṣa naa si ti di baraku fun wọn.

Ṣa o, Bailey ni ko sohun meji toun ṣe gba ọkọ oun laaye lati maa mu ọmu oun ju pe aṣa ọhun jẹ kawọn mejeeji ri ara wọn gẹgẹ bii ololufẹ Pataki, ati pe ifẹ aarin awọn tun n gbilẹ si i lojoojumọ ni, ti wọn ko si fẹ kina ifẹ naa ku lojiji.

Ni ti Ọgbẹni Alexander, o ni aimọye anfaani loun ri gba lati ara pe oun n mu ọmu iyawo oun, lara anfaani ọhun ni pe oun ki i deede dubulẹ asian latigba naa mọ, ati pe o n jẹ kara oun dan daadaa ju atẹyinwa lọ.

Ni kukuru, awọn tọkọ-taya ọhun ti ṣeleri pe laipẹ yii lawọn ẹbi ati ara maa waa ba awọn ṣajọyọ ọmọ tuntun, nitori pe awọn maa too bimọ kẹrin, ko le fun awọn lanfaani lati maa ṣe bii tatẹyinwa.

Leave a Reply