Pẹlu bi ajakalẹ arun koronafairọọsi ṣe tun fẹẹ maa foju han bayii, orilẹ-ede China ti sọ pe oun ko fẹ ki ọmọ Naijiria kankan rin irin-ajo wa siluu awọn lasiko yii, ki kaluku jokoo silu ẹ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni ileeṣẹ to n fun awọn eeyan ni iwe irinna, iyẹn Ẹmbasi orilẹ-ede China, to wa ni Naijiria, nibi kede ẹ pe awọn ko ni i fun awọn orilẹ-ede kan ni iwe irinna, iyẹn fisa, lati wọ ile China lasiko yii.
Lara awọn orilẹ-ede ti wọn sọ naa ni Naijiria, London, Belgium; Luxembourg atawọn mi-in.
Ohun ti ikede ọhun sọ ni pe arun koronafairọọsi to tun fẹẹ bu jade lọna to yatọ yii gan-an lo mu igbeṣẹ ọhun waye.
Bakan naa ni wọn fi kun un pe gbogbo awọn eeyan ti wọn ti ri fisa gba ni nnkan bii ọjọ meji sẹyin, iyẹn ọjọ kẹta, oṣu kọkanla yii, ni wọn jajabọ ninu ofin ati ilana tuntun yii.