Nitori maaluu, Bello lu ọga ẹ ni kumọ pa, lo ba jogun dukia ọkunrin naa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Baba ọlọsin maaluu kan, Yah Muhammed, yoo ti maa kabaamọ lọna ọrun bayii pe oun gba eeyan sọdọ lati waa maa kọṣẹ labẹ oun, pẹlu bo ṣe jẹ pe ọmọọṣẹ rẹ ọhun naa lo pada ran an lọ sọrun apapandodo, to si sọ gbogbo dukia rẹ di tara ẹ patapata.

Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, niṣẹlẹ ọhun waye labule Ṣọku, niluu Isẹyin, nipinlẹ Ọyọ, nigba ti ọdaju ọmọkunrin Fulani kan, Muhammadu Bello, lu ọga ẹ ni kumọ pa nitori ti dukia baba naa wọ ọ loju.

Awọn nnkan ọsin baba yii, ninu eyi ti ogun (20) maaluu pẹlu aguntan mẹrinla (14) wa ni jagunlabi kọkọ ko lọ sọja lati ta.

Ṣugbọn ni Kaara, iyẹn ọja ẹran, niluu Isẹyin, lawọn ọlọpaa ti he e ṣinkun, nibi to ti fẹẹ ta awọn nnkan ọsin ọga ẹ.

Ṣe ohun ti ko ye ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) yii ni pe bi oun ṣe n wa ẹni ti yoo ra awọn ẹran ẹlẹran naa lawọn agbofinro n wa oun paapaa.

Gẹgẹ bi SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe alukoro ileeṣẹ ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, bi Bello ṣe n fi awọn maaluu naa wẹ́lọ̀ kiri ni Kaara, lawọn kan ti ta awọn ọlọpaa lolobo.

Oṣifẹṣọ ṣalaye pe, “nigba ti awọn ọlọpaa tẹle e de abule to sọ pe awọn maaluu ti oun fẹẹ ta wa, nigba naa laṣiiri tu pe oun kọ lo ni awọn nnkan ọsin yẹn, ati pe niṣe lo pa olowo wọn, to si gbẹ ilẹ kuẹkuẹ, to sin baba yẹn sibẹ.

“Oun pẹlu kumọ to fi lu ọga ẹ pa ti wa lakata wa bayii fun iwadii siwaju si i”.

Leave a Reply