Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Alaga ìjọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, Alagba Ayọdele Akande ti pe ipade pajawiri lori ọrọ awọn ajinigbe to wọnu aafin waa ji Oloṣo ti Oṣo-Ajọwa Akoko, Ọba Clement Ọmọọla Jimoh gbe lọ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Ipade yii ni wọn bẹrẹ laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ninu ọgba sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, eyi to wa niluu Oke-Agbe Akoko.
Ninu ipade ọhun ni Alagba Akande ti fi imọlara rẹ han lori ipenija eto aabo to ṣi n tẹsiwaju lagbegbe naa pẹlu gbogbo ilakaka ati igbiyanju Gomina Rotimi Akeredolu lori ọrọ aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Ondo.
Alaga ajọ lọbalọba ti ẹkun ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, Ọba Yisa Ọlanipẹkun, Zaki ti Arigidi Akoko, ninu ọrọ tirẹ ni ohun to ba ni ninu jẹ ni bi awọn janduku kan ṣe le lori laya wọ inu aafin lọọ ko odidi ọba ní papamọra, ti wọn si ji i gbe lọ sibi ti ẹnikan o mọ lati bii ọjọ marun-un sẹyin.
Ọba Olanipẹkun rọ awọn ẹsọ alaabo lati ṣawari Ọba Clement lọnakọna, ko le waa darapọ pẹlu awọn ẹbi ati ara ilu to jọba le lori.
Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni awọn meji kan, Ọgbẹni Samuel ati Emmanuel ti wọn jẹ ẹgbọn fun Ọba Clement ti wọn ji gbe lọ.
Awọn mejeeji yii ni wọn pa ohun pọ lati parọwa si ijọba atawọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Ondo lati tete gbe igbesẹ lori bi aburo wọn yoo ṣe di riri pada laipẹ rara.
Wọn ní awọn ajinigbe naa ti pada din ọgọrun-un Miliọnu ti wọn n beere fun tẹlẹ ku si Miliọnu mẹwaa Naira ti wọn si ti n dunkooko mọ awọn pe pipa lawọn yoo pa Ọba Clement ti awọn ba fi kuna ati tete sanwo ọhun.
Ninu ipade ọhun ni wọn ti fun awọn ẹṣọ alaabo ni wakati mẹrinlelogun pere ki wọn fi wa ọba naa jade nibi yoowu ki wọn le gbe e pamọ si.