Nitori Ọbabinrin Elizabeth, awọn aye n bu Tọpẹ Alabi   

Faith Adebọla, Eko

Titi dasiko yii ni oriṣiiriṣii ọrọ idaro, ibanikẹdun ati oriyin n rọjọ nilẹ wa ati lorileede United Kingdom, iyẹn ilẹ Gẹẹsi, latari iku Ọbabinrin Elizabeth to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an yii, oriṣiiriṣii ọna si lawọn eeyan fi n bọla fun oloogbe naa latigba ti iku rẹ ti ṣẹlẹ.

Ọpọ ikanni ayelujara lo kun fọfọ fun oniruuru ọrọ, orin, ẹfẹ, aworan ati fidio ti wọn fi n sọrọ nipa oloogbe ọhun, bẹẹ si lawọn eeyan pataki pataki lagbo oṣelu, iṣowo, tiata atawọn olorin ilẹ wa naa ko gbẹyin, gbogbo wọn ni wọn n ṣedaro Mama agba Elizabeth to papoda lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un.

Ọkan ninu awọn gbajugbaja onkọrin ẹmi ilẹ wa, Tọpẹ Alabi, naa fi orin ati ohun didun rẹ ṣayẹsi oloogbe naa. Tọpẹ Alabi ṣakojọ awọn fọto mama naa loriṣiiriṣii, lati kekere ẹ titi di arugbo tiku fi de, o si ṣe fidio kan, eyi to gbe soju opo ayelujara Instagiraamu rẹ. Ninu fidio naa, ohun jẹẹjẹ, orin aro, ni Tọpẹ kọ, ede oyinbo lo si fi kọ ọ, bo ṣe sọ ẹdun ọkan rẹ lori iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ lo n gbe awọn fọtọ mama arugbo naa si i lọkan-o-jọkan.

Tọpẹ sọ ninu orin ẹ pe: “Nigba ti mo gbọ nipa iṣẹlẹ yii, ẹru ba mi, o si ba mi lọkan jẹ, bo tilẹ jẹ pe mo mọ pe ibi ti mama lọ sunwọn ju ibi lọ, mo mọ pe ibugbe alaafia ni odikeji ti wọn lọ, ṣugbọn o dun wa pe ẹ fi wa silẹ lai ro tẹlẹ. A o fẹ kẹ ẹ lọ, a o ni i lọkan lati kọrin aro fun yin lasiko yii rara, tori ẹ nifẹẹ gbogbo eeyan, eeyan daadaa si ni yin…” gẹgẹ bo ṣe wi.

Amọ, niṣe lọrọ bẹyin yọ fun Tọpẹ Alabi o, ohun ti olorin ẹmi naa reti latọdọ awọn ololufẹ rẹ kọ lo ba, kaka ti wọn iba fi patẹwọ fun un, ki wọn kan saara si i fun bo ṣe ṣapọnle Elizabeth, oko-ọrọ ati eebu ni wọn fi n ṣọwọ si Tọpẹ Alabi lori fidio to ṣe ọhun, yẹyẹ ati ẹfẹ si lawọn mi-in n fi i ṣe. Koda nibi ti inu bi awọn kan de, gbogbo ẹni to gbiyanju lati gbeja Tọpẹ lori fidio ọhun tun fara kaaṣa, eebu ni wọn tun bu awọn naa.

Ọkan ninu awọn ololufẹ rẹ, Fẹmi, sọ pe: “Aa, Aunti Tọpe, ṣẹ ẹ gbadun ṣa, abi kin ni gbogbo palapala yii!”

Ẹlomi-in, Mista Cross, tun sọ pe, “iru amọju ti i ba ẹkun Ṣaarẹ jẹ wo ree, oju aye lẹ n ṣe yii o, ta a ba fẹẹ sọ ododo. Ko ti i si onkọrin ilẹ Gẹẹsi kan to kọrin ki mama, njẹ ẹ tiẹ mọ nipa itan ilẹ wa paapaa? O ga fun un yin o.”

Obinrin kan, Aanma, kọ ọrọ tiẹ bayii: “Fidio yii pa mi lẹrin-in, o si ri radarada loju mi. Ẹ lẹ o fẹ ko lọ lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un,  ẹni ọdun meloo ni iba waa lọ? Orin aro wo lẹ kọ nigba t’Alaafin Ọyọ ku, tabi nigba ti Ada Amaeh, oṣere tiata ku, to fi waa jẹ Ọbabinrin Elizabeth lẹyin n ṣe oju-aye fun. Iranu!”

Obinrin mi-in, Amina, sọ pe: “Nigba ti mo kọkọ ri fidio yii, mo ro pe awọn kan ni wọn ji orin yin lo lati fi i ṣe fidio ni, ṣugbọn Aunti Tọpẹ, o doju ti mi pẹlu eyi tẹ ẹ ṣe yii o. Aya yin ja pe mama ẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un ku kẹ. O ga o”.

Ni ti Abraham, ohun toun sọ ni pe: “Lara ohun to jẹ ka bọ soko ẹru awọn oyinbo ree, a o si ti i kọgbọn sibẹ. Ẹ wo o bi Tọpẹ ṣe sọ amunisin wa dooṣa.”

Damilọla ni tiẹ sọ pe: “Afi bii ẹni pe Ọbabinrin Elizabeth wa lati Naijiria ni pẹlu bawọn eeyan ṣe n kọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa ẹ, ẹẹn. Oju aye ti ba ti gbogbo yin jẹ. Ẹlomi-in ko de papakọ ofurufu ri laye ẹ debi to maa de ilu London tobinrin naa wa o. Iku Baba Yeye ku, Tọpẹ o kọrin aro bii eyi fun un, ṣiọọ. O waa n sọ pe a o fẹ ko lọ, arugbo bii tiẹ meloo lo ṣẹku saye. Emi o mọ iru awọn Yoruba yii o, ko ye mi fun Tọpẹ rara.”

Bẹẹ lawọn ololufẹ rẹ fi ero wọn han loriṣiiriṣii, lori ikanni Tọpẹ Alabi.

Leave a Reply