Ọlawale Ajao, Ibadan
Wọn ti ni ki ọkan ninu awọn ọga ọgba ẹwọn kan, DSC J.O Ọyaleke, waa wi tẹnu ẹ niwaju adajọ lori ohun to mọ nipa bi ọkan ninu awọn to wa ninu ọgba ẹwọn ti wọn fẹsun pe o lu jibiti ori ẹrọ ayelujara, Otuyalo Oluwadamilọla, ṣe poora lọgba ẹwọn ti wọn fi i si.
Ile-ẹjọ giga kan niluu Ibadan, lo ranṣẹ pe ọga ọgba ẹwọn naa pe ko waa ṣalaye bi Otuyalo ti wọn ni o lu jibiti ẹgbẹrun marindinlaaadọta owo Pọun (£45,000) ṣe poora.
Ajọ to n mojuto ẹsun jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (EFCC), lo mu ọmọkunrin yii lori ẹsun pe laarin oṣu kẹjọ si ikẹsan ọdun 2017, o gba owo kan to le diẹ ni miliọnu mẹrindinlogun (16, 638, 000) ti wọn san si asunwọn Zenith Bank rẹ kan nọmba rẹ jẹ (1005137906), jade, to si sọ pe iṣẹ kan ni oun fẹẹ ba wọn ṣe ti wọn fi san owo naa, ṣugbọn to jẹ pe owo jibiti ori ẹrọ ayelujara, arọndarọnda ni ẹni to sanwo si akanti naa ṣe, o si fẹ ko ba a ṣe agbodegba owo naa lo fi san an si akaunti rẹ.
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ ni wọn fi kan Oluwadamilọla, to si ni oun ko jẹbi.
Eyi ni wọn tori ẹ gbe e lọ sile-ejọti adajọ si paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i pamọ si ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ mi-in yoo fi waye. Eyi lo mu ki ẹni ti wọn fẹsun kan naa di ero ọgba ẹwọn Abolongo, niluu Ọyọ.
Nigba to di ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun to kọja, to yẹ ki ẹni to wa nidii ẹjọ naa mu Damilọla wa siwaju Adajọ Uche Agomoh ki igbẹjọ le bẹrẹ ni wọn ko ri i. Ni wọn ba ranṣẹ pe ọkan ninu awọn ọga ọgba ẹwọn yii lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii, pe ko waa ṣalaye ibi ti ọmọkunrin ti wọn fi pamọ si akata wọn wa.
Oyaleke sọ fun adajọ pe ọmọkunrin ti wọn n wa yii wa ninu awọn ẹlẹwọn bii irinwo ati ẹyọ kan (401) ti wọn sa lọ ni ọgba ẹwọn Abolongo lọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ti awọn janduku kan ya wọ inu ọgba ẹwọn naa to wa niluu Ọyọ.
O ni gbogbo agbara lawọn alakooso ọgba ẹwọn ti n sa lati ri i pe wọn ri ọdaran naa mu.