Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Apapọ ẹgbẹ Onigbagbọ (CAN), ẹka tipinlẹ Ondo ti fi ẹhonu han ta ko ofin tijọba fi de isọ-oru aṣe wọ inu ọdun tuntun to n bọ lọna.
Alaga ẹgbẹ naa, Ẹni-Ọwọ John Ọladapọ ṣalaye fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii, lo ti fidi rẹ mulẹ pe o di dandan ki isọ-oru naa waye gẹgẹ bii iṣe awọn Onigbagbọ lọdọọdun.
O ni ki i sohun to bojumu rara pẹlu bijọba ṣe sare lọ sori redio lati kede fifi ofin de ayẹyẹ ti wọn ti n ṣe láti ọjọ pipẹ wa lai fun awọn gbọ tẹlẹ.
Ẹni-Ọwọ Ọladapọ ni ọrọ ọdun Keresi ati ọdun tuntun kọja ohun tí ẹni kan yoo jokoo si kọrọ kan nínú ọfiisi rẹ, ti yoo si maa da kọwe aṣẹ lori ohun to kan gbogbo araalu gbọngbọngbọn.
O ni o yẹ kijọba kọkọ ṣepade, ki wọn si gbọ ero ọkan awọn tọrọ kan, ki wọn too maa gbe iru ipinnu bẹẹ jade.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni alaga igbimọ to n mojuto itankalẹ arun Korona nipinlẹ Ondo, Ọjọgbọn Adesẹgun Fatusi, fi atẹjade kan sita lorukọ ijọba, ninu eyi to ti kede fifi ofin de isọ-oru aṣewọ ọdun Keresi ati ọdun tuntun, latari bi arun Korona tun ṣe n ṣọṣẹ lọwọ lawọn apa ibi kan lorilẹ-ede yii.
Alaga ọhun ni ko si ile-ijọsin, ile-ijo, tabi ile-ọti to gbọdọ sohunkohun lẹyin aago mẹwaa alẹ.