Monisọla Saka
Gbajumọ olorin taka-sufee ilẹ wa tẹnu rẹ ki i dakẹ nni, Habeeb Okikiọla Ọmọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable tabi Zaazu Zeh, ti fibinu sọrọ latari ofin ti ajọ EFCC fi n mu araalu lori owo Naira.
Gẹgẹ bawọn eeyan ṣe n ṣọra lati nawo lode ariya, ki wọn ma baa ko si panpẹ ajọ naa, Portable ni bii ẹni dina ijẹ mọ awọn ni.
Latigba ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorilẹ-ede wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti fi ọkunrin bii obinrin alafẹ ori ayelujara, Idris Okunẹyẹ, ti wọn n pe ni Bobrisky jofin, ti wọn si tun wọ ọmọ jayejaye toun naa maa n nawo yalayolo, Cubana Chief Priest, lọ siwaju adajọ, lawọn eeyan ti n bẹru ati maa nawo nibi ayẹyẹ.
Ọrọ yii lo ka Portable lara, to fi n beere pe ṣe wọn fẹ kawọn lọọ gbebọn lati maa jale ni. O ni lati ayebaye lo ti jẹ pe wọn maa n gbe owo wa soju agbo lati na an fun elere ni, o ṣe waa jẹ nigba tawọn ni wọn fẹẹ dina ijẹ yii, ti wọn fẹẹ maa fi ebi pa awọn.
Pẹlu itara ni ọkunrin to maa n pera ẹ ni bukata ijọba apapọ yii fi n sọrọ, bẹẹ lo fi ye wọn pe niwọn igba to ba ti jẹ pe owo iṣẹ oun loun n jẹ, ti wọn ba gbidanwo ati fofin gbe oun, oun maa sọ pe oun ko jẹbi ni ati pe nigbẹyin gbẹyin, awọn ni wọn tun maa fun oun lowo.
“Ọmọ iya mi, ẹ gbagbe oṣi, ebi n pa awọn eeyan. Ọpọlọpọ awọn eeyan to kawe ko riṣẹ, awọn eeyan lọ sileewe, ọkada ni wọn pada n gun, ọpọlọpọ n ṣe kọndọ lẹyin ọkọ. Ẹyin temi, ki lo n ṣe yin na? Ki lo de tawọn ọlọpaa ki i gun Benz, ki lo de ti ṣọja ki i gun Benz? Eeyan kọ’ṣẹ, to ba ya, wọn aa waa sọ pe ọrẹ wa lawọn ọlọpaa. O daa, ọrẹ wa ni wọn, ọrẹ wa ni ọlọpaa, ni gbogbo igba, ọrẹ wa ni wọn. Awọn ni wọn n ṣọ wa.
“Ta lawọn eeyan ti wọn n dunrun mọ wa yii? A maa dunrun mọ yin o. Eeyan to ba ni ka ma gbele aye mọ, pe ka ma nawo bo ṣe wu wa mọ, nitori nigba ti ebi n pa mi, ti ko sowo, ti mo n mu gaari, mo ranti pe ko sẹnikẹni. Igba ti mo waa tiraka, ti mo jade tan, tẹ ẹ ba mu mi, tẹ ẹ ba ṣe ohunkohun, mo maa ni mi o jẹbi ni o. Mi o jẹbi yin laye, mi o jẹbi yin lọrun. Wọn maa ni ki n maa lọọle.
“Niwaju Ọlọrun, ti Ọlọrun ba beere pe ṣe o jẹbi, sọ pe mi o jẹbi wọn, mi o jẹbi yin. Mi o jẹbi yin, mi o gbọ oyinbo, Yoruba ni mo maa sọ. Mi o jẹbi yin laye, mi o jẹbi yin lọrun, ọmọ Ọlọrun ni mi, mi o ni jẹbi. Nnkan tawọn kan ṣe laye ti wọn ko ṣe gbe, Ọlọrun ti fun wa ka ṣe e gbe, aṣegbe wa laye.
“Ẹ jọọ, nitori Ọlọrun, K1 de Ultimate, ode orin yin la ti ba a ti wọn maa n nawo. Pasuma, wọn maa n gbe bọndu owo wa si ode ere yin ni. Owo lo n ṣe koriya fawa olorin. Nisinyii, ko sowo ninu kinni yii mọ bayii. Ere bọọlu niyẹn, a mọ ọn gba amọ a o gba ife-ẹyẹ ri. Orin ati amuluudun lo n gbe Naijiria larugẹ bayii. Amuluudun lo n mu owo wọle o. Wọn ti tun fẹẹ di ọna ibi ti a ti n jẹ.
“Ọna epo rọbi, wọn ti di i, ẹ ko ri epo mu mọ. Wọn di ọna epo, ọna dọla naa, ẹ di i, ọna orin to tun n mu owo wa, ẹ tun fẹẹ di i. Ṣe ka maa gbebọn ni, ṣe ka maa lọọ jale ni? A ko ṣe owo baṣubaṣu, a nifẹẹ owo, a si n fẹ owo, a nilo owo. Owo ni ẹṣọ alaabo wa, owo lawọn igiripa (bouncer) ti wọn tẹle wa kiri. Ṣe ẹ n gbọ, Ọlọrun ni aburanda wa. Awọn to kowo jẹ da? Awọn to ba eto ọrọ aje wa jẹ da? Ẹ lọọ ran wọn lẹwọn. Awọn eeyan pọ tẹ ẹ maa ko o. Iyẹn ọtọ, awọn to fọ eto ọrọ aje wa, ki lo ṣe eto ọrọ aje to fi wo, ki lo kọ lu eto ọrọ aje?
“Iyẹn ni kẹ ẹ beere, awọn kan wa to jẹ pe ole ni wọn, ẹ lọọ gbe wọn. Iru awa, tẹ ẹ ba gbe wa, owo ode ere lẹ maa ba ninu akanti wa o. Iru emi, tẹ ẹ ba mu mi, gbese lẹ gbe o. Awọn kan ti jẹ owo show (ode ere), awọn promoter ti jẹ owo show. Awọn to ni ode, wọn o ni i gba, owo show, owo geeti ti mo ti gba, owo olowo, owo party, owo ikomọ, owo kilọọbu (club) ti mo ti gba, wọn maa jade fun mi. Ṣe ẹ n gbọ, arọgidigba, ẹ maa gbe wọn ju silẹ. Tẹ ẹ ba gbe mi, ẹ maa gbe mi ju silẹ, ẹ tun maa tẹ owo si mi ni”.
Tẹ o ba gbagbe, o ti kọkọ gbe fidio kan jade, nibi to ti n bẹ awọn EFCC pe ti wọn ba ri fidio oun ti oun ti nawo, o ni igba aimọ ni, oun ko jẹ ṣe bẹẹ mọ bayii, nitori lẹyin Ọlọrun, ijọba lo kan. Bẹẹ lo ni oun yoo maa lo anfaani naa lati polongo fun awọn eeyan pe ki wọn ma ṣe owo Naira baṣubaṣu.
Ṣugbọn o jọ pe ẹọ ko ṣoju mimu pẹlu bi ọmọkunrin naa ṣẹ pa oun da bayii, to si n sọ pe igbesẹ awọn EFCC ti n ṣakoba fun awọn lode ere. O ni wọn ko na owo fun awọn ni kilọọbu mọ, bẹẹ ni wọn ẹru si n ba awọn eeyan lode ariya lati nawo fun olorin. Beẹ owo ti wọn n na fawọn yii lo maa n jẹ ki ori awọn wu lati kọrin.
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ kawọn olorin ma kogba sile nigba ti wọn ko ba rẹni nawo fun wọn lode ere