Monisọla Saka
Minisita fọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti kọwe sigbimọ awọn gomina lati ṣepade pẹlu wọn lọna ati pese aaye ninu awọn ọgba ẹwọn jake-jado orilẹ-ede yii. Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni agbẹnusọ Minisita ọhun, Ṣọla Fasure, ṣalaye ọrọ naa.
Arẹgbẹṣọla ni, ni nnkan bii oṣu kan si isinyii, oun yoo ṣepade pẹlu awọn gomina lati le jọ fori kori, ki awọn le tu bii ida ọgbọn awọn ẹlẹwọn silẹ lawọn ọgba ẹwọn ilẹ Naijiria.
O ni eleyii ṣe pataki gẹgẹ bo ṣe jẹ pe awọn ẹlẹwọn bii ida aadọrun-un ni wọn wa latimọle fun oniruuru ẹsun, bẹẹ lo jẹ pe ida aadọrin(70%) ninu wọn, to le ni ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin(75,635) ni wọn o ti i ṣedajọ wọn.
O tẹsiwaju pe awọn to jẹ pe ofin ijọba apapọ ni wọn ṣẹ si ko to ida mẹwaa rara. O ni pupọ ninu awọn to wa latimọle yii lo jẹ pe ofin ipinlẹ ni wọn lu, nitori bẹẹ si ni wọn ṣe n ṣẹwọn nipinlẹ koowa wọn. O fi kun un pe, o ṣe pataki kawọn ṣe adinku sawọn to wa ni ọgba ẹwọn ọtalenigba ati mẹta (263) to wa lorilẹ-ede yii nitori ọpọ awọn ẹlẹwọn yii ni ko yẹ ki wọn wa latimọle.
Fasure ni, “Minisita ti kọwe sẹgbẹ awọn gomina, ṣugbọn wọn ko ti i jọ jokoo ipade nitori wọn maa jọ sọrọ, awọn naa ni wọn si maa fun un lọjọ ti ipade ba maa waye. Nitori ki wọn le jọ ṣepade naa lo ṣe kọ lẹta si wọn, ṣugbọn wọn o ti i fesi”.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, naa ni ijọba apapọ ṣalaye pe awọn ẹlẹwọn to le ni ẹgbẹrun mejila ni awọn tu silẹ kaakiri ipinlẹ lorilẹ-ede yii laarin ọdun mẹfa sẹyin, ni ibamu pẹlu ofin wiwa aaye ninu ọgba ẹwọn.