Nitori ọmọ yunifasiti ti wọn niyawo Buhari ni ki DSS ti mọle, awọn akẹkọọ fẹẹ ṣewọde

Faith Adebọla

Bi kannakanna ba na ọmọ ẹga, ija lo n kọwe si, owe yii lawọn ẹgbẹ akẹkọọ nilẹ wa, National Association of Nigerian Students, NANS, fi n rọ awọn alaṣẹ atawọn agbofinro lati tu ọkan lara wọn ti wọn gbe ju sahaamọ DSS, Ọgbẹni Mohammed Aminu, silẹ, wọn lawọn maa bẹrẹ ifẹhonuhan to lagbara lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ta a wa yii, latari mimu ti wọn mu akẹkọọ fasiti ijọba apapọ, Federal University, to wa ni Dutse, nipinlẹ Jigawa.

Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ọhun, Usman Babambu, sọ ninu atẹjade kan to fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu Kejila yii, pe gbogbo ọna tawọn mọ lati yanju ọrọ yii nitubi-inubi, ko ma la ariwo lọ, lawọn ti tọ, sibẹ, awọn ko ri i yanju, ko sohun tawọn tun le ṣe ju ifẹhonuhan ati iwọde lọ.

Atẹjade naa ka lapa kan pe:

“Latari bi gbogbo isapa wa lati lo oniruuru ọna ipẹtu-saawọ ṣe fori ṣanpọn, ko si ọna mi-in ta a le lo ju ka woju ara wa lori ọrọ yii, lati ri i pe wọn tu akẹkọọ ẹlẹgbẹ wa kan tawọn agbofinro mu sahaamọ lọna aitọ, ti wọn si n fiya jẹ ẹ, ti wọn n foju ẹ gbolẹ silẹ. Ipinnu ẹgbẹ NANS ni lati bẹrẹ iwọde ti ko lopin, afi ti wọn ba tu akẹkọọ naa silẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni obinrin ajijagbara ilẹ wa kan, Aisha Yesufu, ti sọrọ si iyawo Aarẹ orilẹ-ede yii, Aisha Buhari, fun iwa ta ni yoo mu mi to hu gẹgẹ bo ṣe paṣẹ pe ki wọn sọ Aminu Mohammed si atimọle lori ọrọ odi ti wọn lo sọ si i lori ẹrọ ayelujara.

Muhammed, ọdọmọkunrin akẹkọọ to wa nipele to kẹyin lẹka ẹkọ imọ nipa ayika (Environmental Management and Toxicology), nileewe giga Federal University Dutse, ipinlẹ Jigawa, ni wọn lo fi ede Hausa kọ ọrọ kan sabẹ fọto Aisha Buhari lori ẹrọ alatagba Twitter rẹ ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii pe, “iya ti tobi si i pẹlu owo awọn araalu to n jẹ”.

ALAROYE gbọ pe ọrọ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ tawọn olukọ Fasiti ilẹ wa (ASUU) gun le nigba naa, tawọn ijọba si kọ ti wọn o ṣe nnkan kan si i lo mu ki akẹkọọ naa sọrọ naa lati fi ẹdun ọkan rẹ han. Ohun ti wọn lọmọkunrin naa ni lọkan ni pe, owo to yẹ ki wọn fi yanju aawọ laarin ijọba atawọn ẹgbẹ ASUU loun fi n ṣe ararindin, tiya si n jẹ awọn akẹkọọ gẹgẹ bi wọn ṣe n fẹsẹ gbalẹ kiri nigba ti wọn ko ri ileewe lọ.

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) ọhun ni wọn lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ (DSS), lọọ gbe ninu ọgba ileewe wọn ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla yii. Wọn ni wọn kọkọ fi lulu da batani si i lara, lẹyin naa ni wọn fi panpẹ ofin gbe e lọ si itimọle.

Lẹyin eyi ni wọn foju rẹ bale-ẹjọ. o jọ pe abẹlẹ ni wọn ṣe e,  wọn l’Adajọ Halilu Yusuf tile-ẹjọ giga apapọ kan l’Abuja lo paṣẹ ki wọn ṣi tọju afurasi naa sahaamọ ọgba ẹwọn to wa ni Suleja, nipinlẹ Niger, na, fun ẹsun pe o bẹnu atẹ lu iyawo Aarẹ.

Nigba to n fi aidunnu rẹ han lori iṣẹlẹ yii, Aisha Yesufu ni, “Oju gba mi ti fun Aisha Buhari, niṣe lo yẹ ko dọwọ boju. Iwa ika ti ko ba ofin mu rara leyi. Ọkọ ẹ ti ju ida mẹtalelọgọta (63%) awọn ọmọ Naijiria sinu iṣẹ ati iya ti ko mọ niwọnba, ti wọn n ba iyẹn yi lọwọ na. Ṣe loootọ kọ waa ni pe awodi wọn n jẹun epe sanra, ṣe òógùn awọn ọmọ Naijiria kọ lo mu un tobi gẹgẹ bi wọn ṣe wi? Awọn ti ju ara wọn sinu agbami ọla ati ọrọ̀ ni tiwọn. Ta loun, bawo ni tiẹ ṣe jẹ to fi maa ni ki wọn lọọ fi panpẹ ofin gbe eeyan kan nitori pe wọn lo ti jẹ ọrọ̀ awọn alaini?

“Nigba to mọ pe agbara oun to bayii, ki lo de ti ko ti lo o lati gba awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa nigbekun silẹ?”

Titi dasiko yii lawọn eeyan n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, paapaa lori ẹrọ ayelujara, wọn koro oju siwa ti Aisha Buhari hu yii, wọn niṣe lobinrin naa n fọwọ ọla gba akẹkọọ yii loju, wọn si bẹnu atẹ lu bijọba ṣe fọwọ lẹran lori ọrọ yii.

Leave a Reply