Nitori ọrọ Bobrisky, eyi lohun tile-ẹjọ ṣe fun Very Dark Man

Jọkẹ Amọri

Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ni ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Eko paṣẹ pe ki ọmọkunrin to maa n sọrọ lori ayelujara, to tun tu aṣiri awọn ọrọ ti Bobrisky sọ sita, Martin Otsem, ti gbogbo eeyan mọ si Very Dark Man, gbe gbogbo awọn ọrọ to gbe jade nipa agbẹjọro ilẹ wa nni, Fẹmi Falana ati ọmọ rẹ, Fọlarin Falana, kuro lori ayelujara ni kiakia.

Ninu idajọ ti Onidaajọ Dawodu gbe kalẹ lo ti sọ pe awọn olupẹjọ, iyẹn Fẹmi Falana ati Fọlarin, sọ pe olujẹjọ mọ pe awọn ọrọ ti Bobrisky sọ ki i ṣe otitọ rara. Pẹlu pe o mọ pe irọ ni awọn ọrọ naa, o ṣi tun gbe e jade, eyi ti o ti ko ipalara ati ibanilorukọ jẹ fun awọn mọlẹbi naa.

Wọn fi kun un pe pẹlu bi ọrọ naa ṣe jẹ irọ to jinna soootọ to, Very Dark Man ṣi n gbe sori ayelujara, eyi to ti di atagba, ti ọpọ eeyan si n pin in kaakiri bii mọsa saara lori ayelujara.

Ile-ẹjọ waa paṣẹ pe ko gbe awọn ọrọ naa kuro ni gbogbo ori ayelujara ati awọn ibi to ti pin in ka de.Bakan naa ni Dawodu ni ki wọn mu iwe to pọn ọn ni dandan fun un lati gbe awọn igbesẹ ti awọn olujẹjọ beere fun ko too di pe yoo lẹtọ lati pẹjọ ta ko ibeere wọn lọ fun un tabi agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Deji Adeyanju.

Lara ohun ti Falana at’ọmọ rẹ n beere fun ni pe ki ọmọkunrin to gbe ọrọ naa jade gbe e ekuro ni gbogbo ori ayelujara.

Yatọ si eyi, o gbọdọ tọrọ aforiji lori gbogbo ikanni ayelujara rẹ. Bakan naa lo tun gbọdọ san miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira gẹgẹ bii owo ibanilorukọ jẹ.

Adajọ tun fi kun un pe wọn le lọọ lẹ iwe naa tabi ki wọn fun agbẹjọro olujẹjọ, ko ma baa sọ pe oun ko ri i, tabi gbọ nipa rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ọkunrin ti wọn n pe ni Very Dark Man yii gbe itakurọsọ kan to waye laarin ọmọ jayejaye to maa n mura bii obinrin nni, Idris Okunnẹyẹ ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky jade, nibi to ti sọ pe oun fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, (EFCC) ati awọn ọga ọgba ẹwọn kan lowo lori ẹjọ ṣiṣe owo ilẹ wa baṣubaṣu ati ṣiṣe agbodegba fun awọn kan lati maa ba wọn fi asunwọn rẹ gbe owo lọ sibomi-in lowo lati rẹ ẹjọ naa ri.

Nibẹ lo ti sọrọ ba ọmọ Fẹmi Falana pe oun pe e ki o ya oun lowo, bakan naa loun beere iranlọwọ bi oun ṣe le gba aforiji ijọba iyẹn (Presidential pardon) lọwọ rẹ, to si beere fun miliọnu mẹwaa Naira.

Awọn ọrọ wọnyi atawọn mi-in ti Bobrisky sọ lo tẹ VDM lọwọ, to si tu aṣiri naa sita. Ṣugbọn ti agba agbẹjọro naa ni o gbe igbesẹ ọhun lati ba orukọ oun at’ọmọ oun pẹlu idile oun jẹ ni.

Eyi lo mu ko gbe ọmọkunrin naa lọ sile-ẹjọ, ti kootu si fọwọ si i pe ko gbe fọnran naa kuro ni ori ayelujara ko tiẹ too di pe igbẹjọ kankan maa waye lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Leave a Reply