Faith Adebọla
Aṣa ti wọn maa n da pe ‘bolounjẹ ri ni to roju, aa si fi aijẹ tẹ ẹ,’ lo wọ ọrọ ti oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar, fi fesi ọrọ si bi Gomina ipinlẹ Rivers ṣe sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Keji yii, pe oun ti pa ero da lori wiwọgi tawọn wọgi le iyọnda lilo papa iṣere Adokiye Amesiamaka fun eto ipolongo ibo aarẹ ti ikọ ipolongo ibo Atiku lawọn fẹẹ ṣe. Atiku lawọn o nifẹẹ si papa iṣere naa mọ o, awọn ti ribomi-in tawọn fẹẹ lo, tori eeyan ti o ṣee dara de kan bayii ni Wike.
Ọrọ yii waye latari fa-n-fa-a to ti n ṣẹlẹ laarin Gomina Wike, Atiku ati awọn adari ẹgbẹ oṣelu wọn, PDP.
Ṣe lọjọ kọkanla, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii ni ijọba ipinlẹ Rivers kọwe si igbimọ ipolongo ibo fun Atiku pe awọn ti faṣẹ si i, awọn si ti gba ki wọn lo papa iṣere nla naa fun ayẹyẹ ipolongo ibo ti wọn fẹẹ waa ṣe loṣu Keji yii, tawọn tọhun si ti n foju sọna lati lo ibẹ.
Afi bo ṣe di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni yii, ti ijọba Rivers tun fi iwe mi-in lede, nibi ti wọn kọ ọ si pe awọn ti wọgi le aṣẹ ati iyọnda tawọn fun Atiku ni Januari tẹlẹ, wọn lawọn o ni i yọnda papa iṣere naa fun wọn mọ, ki wọn wa ibi ti wọn ti fẹẹ ṣeto ipolongo ibo wọn siwaju.
Idi ti wọn sọ po fa a tawọn fi wọgi le iyọnda ọhun ni pe alami ati akiyesi kan tijọba Rivers ṣe fihan pe awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan nipinlẹ naa n ṣe wọle-wọde pẹlu ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, iwa ọdalẹ si niru nnkan bẹẹ, tori PDP lo n ṣakoso Rivers lọwọlọwọ, ati pe iru iwa bẹẹ lo mu komi tẹyin wọgbin lẹnu fawọn lasiko eto idibo gbogbogboo to wọle de tan yii.
Ni pato ni atẹjade naa sọ pe aṣiri ti tu sijọba Rivers lọwọ pe awọn kan lara ikọ ipolongo ibo Atiku, ẹka ti Rivers, n ṣiṣẹ pẹlu Tonye Patrick Cole, to jẹ igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC wọn, o si ṣee ṣe ki ija ati laasigbo bẹ silẹ lasiko ti Atiku ba de saarin wọn.
Amọ, ọsẹ kan lẹyin naa, iyẹn lọjọ Tusidee, ọsẹ yii, ni Wike tun kede nibi eto ipolongo ibo fun oludije funpo gomina ipinlẹ Rivers labẹ asia PDP, pe awọn ti tun pa ero da o, ijọba oun ti gba, oun si ti faṣẹ si i pe ki wọn lo sitediọmu ọhun fun Atiku.
Nigba to di Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji yii, ni Agbẹnsọ fun Atiku ati igbimọ ipolongo rẹ ni Rivers, Ọmọwe Leloonu Nwibubasa, sọ pe awọn o nilo sitediọmu Wike mọ.
Nwibubasa ni: “A gbọ ọ lanaa pe Wike kede p’awọn ti tun yọnda papa iṣere naa fun ilo ipolongo ibo Atiku, wọn lawọn ti peroda lori ipinnu awọn tẹlẹ.
“Ẹ jẹ ki n sọ ọ fun yin kedere pe Atiku ati igbimọ ipolongo ibo rẹ ko nilo sitediọmu naa mọ, a o nifẹẹ si ẹbun ‘gba ma sọ mi lẹnu’ ẹ, tori a ti ri i pe ki i ṣẹnikan teeyan le gbara le.
“Ṣe o sa a nidii to fi wọgi le iyọnda papa iṣere naa tẹlẹ, o laṣiiri kan tu sawọn lọwọ, ṣe aṣiiri naa o tun waa tu si i lọwọ mọ ni, to fi tun loun ti yọnda ẹ bayii? Ṣe igbimọ ipolongo ibo Atiku to lo n ṣe wọlewọde pẹlu APC lati daluru o tun ṣe bẹẹ mọ ni.
Iwe ni Wike kọ to fi faṣẹ si iyọnda alakọọkọ, iwe naa lo kọ si wa to fi loun o yọnda mọ, nigba to pero da yii, iwe naa lo yẹ ko kọ, ki i ṣe ko fẹnu sọ ọ nibi ipolongo ibo ẹ.
“Ohun ta a kan fẹ kawọn eeyan ipinlẹ Rivers mọ ni pe, wọn o ni olori gidi to ṣee fọkan tẹ, asọrọ-ana-di-bami-in eeyan kan ni gomina wọn.”