Adewale Adeoye
Ibinu ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nilẹ lọrọ da fun ọkunrin kan, Abdullahi Audu, pẹlu bo ṣe tori ọrọ ti ko to nnkan, to fada ge ọwọ ọrẹ rẹ, Usman Muhammed, mejeeji ja bọ silẹ.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti lawọn maa too bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, to fi di pe awọn ọrẹ ọhun doju ija kọra wọn, ti wọn si fohun ija oloro bara wọn ja debii pe awọn mejeeji wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun bayii.
ALAROYE gbọ pe awọn ọrẹ meji ọhun ni wọn jẹ Fulani, ti wọn si n gbe lagbegbe Ogunmakin, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. Ọjọ Aje, Monde, ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lawọn ọrẹ mejeeji yii wa lẹnu faaji kekere kan, nibi ti wọn ti n mu ọti ẹlẹridodo lọwọ. Ko waa sẹni to le sọ ohun to ṣokunfa ija to bẹ silẹ laarin awọn mejeeji, bo tilẹ jẹ pe awọn kan to wa nibẹ sọ pe Audu lo kọkọ yọ ada penpe kan jade latinu apo to wa lẹgbẹẹ rẹ, to si fi ge ọwọ Muhammad danu. Bi Muhammadu ti wọn ge ọwọ rẹ ṣe ri i pe wọn ti sọ oun di alaabọ ara, ti ẹjẹ si n da gidigidi lara rẹ loun paapaa ti fa ọbẹ aṣoro kan yọ lati inu apo rẹ, to si ki i bọ Audu lẹgbẹẹ ikun, bo ṣe fẹẹ fa ọbẹ naa yọ ni ifun Audu n tẹle ọbẹ naa, toun naa si n ke igbe oro buruku laarin awọn ẹrọ. Loju-ẹsẹ lawon mejeeji ti ṣubu lulẹ, ti wọn si n jẹ irora buruku nilẹẹlẹ ti wọn wa.
Seriki agbegbe naa, Alhaji Wakili, lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan Owode Ẹgba leti, ko si pẹ rara tawọn to jẹ ọrẹ wọn fi sare gbe wọn digba-digba lọ sileewosan tijọba to wa lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye fun itọju to peye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọloọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ pe oun ti gbọ si iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati fidi ootọ mulẹ nipa ohun to ṣẹlẹ laarin wọn.
Alukoro ni, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ede aiyede kekere kan bẹ silẹ laarin awọn ọrẹ meji naa, kawọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti doju ija kọra wọn, wọn ṣe ara wọn leṣe gidi, ṣugbọn ti wọn ti n gbatọju lọwọ nileewosan bayii.