Faith Adebọla, Eko
Ahamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lawọn baale ile mẹrin kan ti n jẹwọ ẹṣẹ wọn bayii, Fatai Taiwo, ẹni ogoji ọdun, Sunday Onilede, ẹni ọdun marundinlogoji, Rasaki Hazan, ẹni ọdun marundinlogoji ati Ibrahim Abdullahi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ọmọ ẹgbẹ OPC (Oodua Peoples Congress) lawọn mẹrẹẹrin.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ọrọ kan ṣe bii ọrọ laarin wọn pẹlu Ọgbẹni Chidi Tochukwu, o si di ariyanjiyan gidi, lawọn mẹrẹẹrin ba ki Chidi mọlẹ, wọn lu u nilukulu, wọn tun gun un lọbẹ, lọrọ ba ja si iku.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, sọ pe Ojule kẹrindinlaaadọrin, Opopona Arọbadede, lagbegbe Bariga, ipinlẹ Eko, ni oloogbe to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji naa n gbe, ṣugbọn wọn ni Opopona Temple, ni Bariga, kan naa niṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.
O lawọn aladuugbo gbọ nigba tawọn ọmọ OPC yii n ṣe fa-a-ka-ja-a pẹlu Tochukwu lori ọrọ kan, ṣugbọn ko sẹni to fura pe ariyanjiyan wọn le la ti lilu lọ, debi tọrọ maa di ti a n yọ ọbẹ sira ẹni.
Iboosi ti Tochukwu ke nigba ti wọn gun un lọbẹ, to si bẹrẹ si i pọkaka iku, lo mu kawọn eeyan sare debẹ, wọn si gbe ọkunrin naa digbadigba de ọsibitu Jẹnẹra Bariga, awọn dokita si sapa lori rẹ, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, ọkunrin naa dagbere faye.
Awọn aladuugbo naa ko jẹ kawọn afurasi apaayan yii ribi sa lọ, wọn pe awọn ọlọpaa teṣan Bariga lori aago, awọn ni wọn waa fi pampẹ ofin gbe gbogbo wọn.
Ọrọ yii ti detiigbọ kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, o si ti paṣẹ pe ki wọn taari wọn sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba. Ibẹ ni gbogbo wọn wa, ti wọn n ran wọn lọwọ lẹnu iwadii wọn.
Alukoro ni abọ eleyii lawọn n duro de, ki wọn le foju awọn afurasi ọdaran yii bale-ẹjọ laipẹ.