Nitori ọrọ ti ko to nnkan, Esther gun ọrẹkunrin ẹ lọbẹ pa

Faith Adebọla, Eko

Abamọ, a o ṣe e, a ṣe e tan, o daapọn, bẹẹ lọrọ ri fun ọdọmọbinrin tọjọ ori ẹ o ko ju ọdun mọkandinlogun lọ, Esther Paul, ẹni to ti n geka abamọ jẹ lakolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ bayii. Niṣe lọmọbinrin naa fa ọbẹ yọ si ọrẹkunrin rẹ, Sadiq Owolabi Dahiru, ẹni ọdun mọkanlelogun, lasiko ti ariyanjiyan waye laarin wọn, lo ba fibinu gun un lọbẹ, o si pa a fin-in-fin-in.

Owurọ ọjọ Aiku, Sannde, ogunjọ, oṣu Kọkanla yii, niṣẹlẹ naa waye nile ọrẹkunrin rẹ ọhun to wa l’Opopona Ọba Amusa, adugbo Agungi, lagbegbe Lẹkki, l’Erekuṣu Eko lọhun-un.

ALAROYE gbọ pe mama oloogbe naa ko si lọdọ baba rẹ mọ, wọn ti kọra wọn silẹ, ọdọ ọkọ mi-in, Ọgbẹni Kazeem Ọbafunṣọ, tobinrin naa wa loun atọmọ rẹ ti wọn pa yii n gbe.

Ko sẹni to le sọ pato ohun to faja laarin wọn to fi dọrọ a-n-yọbẹ-sira ẹni laarin awọn ololufẹ mejeeji.

Wọn lafurasi ọdaran naa lo wa ọrẹkunrin ẹ wa sile laaarọ ọjọ buruku ọhun, kọrọ too dija laarin wọn.

Ọgbẹni Ọbafunṣọ lo lọọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa pe ọmọbinrin kan ti pa ọmọ iyawo oun, lawọn agbofinro ba tẹ le e.

Nigba ti wọn dọhun-un, wọn ba Sadiq ninu agbara ẹjẹ to ti rin aṣọ rẹ gbindin, ṣugbọn ọmọbinrin to ṣiṣẹ laabi yii ti kuro nibẹ. Wọn sare gbe e lọ sileewosan Evercare Hospital, to wa lagbegbe Lẹkki Phase 1, ibẹ lawọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe ẹni ti wọn gbe wa ọhun ti ku patapata.

Lẹyin eyi ni wọn dọdẹ ọmọbinrin apaayan yii lọ sile to n gbe, ọwọ wọn si tẹ ẹ.

Wọn ni wọn ti gbe oku ọrẹkunrin Esther lọ sile igbokuu-si kan fun ayẹwo lati fidi iku to pa a mulẹ. Bakan naa ni afurasi naa ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to lọọrin.

Lẹyin iwadii ni wọn maa gbe igbesẹ ofin to kan lori iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply