Isaau Falana, ẹni ọdun marundinlọgọta (55), ko le sun ile ẹ mọ bayii, idi ni pe ẹka to n ri si ipaniyan ni wọn fi i pamọ si latari mọlẹbi ẹ, Badmus Rafiu, to lu pa nitori iyẹn dana sungbo nítòsi oko Ishau.
Ọjọ kẹrinla, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, lọwọ ba Ishau, iyẹn lẹyin to jẹwọ fawọn ọlọpaa teṣan Ayetoro to lọọ mu un, pe oun fi okun de Rafiu lọ́wọ́ atẹsẹ, oun si bẹrẹ si i figi lu u titi to fi daku, oun si fi i silẹ sibẹ, oun gba ile lọ ni toun.
Nigba to n dahun idi to fi lu ẹni to jẹ famili rẹ daku, to fi di pe iyẹn ku sibẹ, Falana sọ pe oko awọn kan to wa ni Oluwaṣogo, lagbegbe Ijaka Isalẹ, ni Rafiu dana sun, eyi to wa nitosi oko toun.
Afurasi yii sọ pe ohun to dija laarin oun ati ẹ niyẹn, tawọn fi bẹrẹ si i ja, toun si de e lọwọ atẹsẹ, toun n fi igi lu u titi to fi daku. O ni ṣugbọn oun ko mọ pe yoo ku.
Ko sẹni to mọ pe Rafiu ti ku sinu oko, iya rẹ lo lọ soko naa lọjọ keji to ba oku ọmọ rẹ nibẹ. Lẹyin naa ni aburo oloogbe to mọ nipa iṣẹlẹ naa lọọ fẹjọ sun ni teṣan Ayetoro, ti wọn fi lọọ mu Falana to si jẹwọ ohun to ṣe.
Iwa ipaniyan to hu naa lo mu un wa latimọle bayii, ibẹ ni yoo si gba de kootu, gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣe wi.