Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọlọrun nikan lo le ko pasitọ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta kan, Emmanuel Adebayọ, yọ ti ko fi ni i ṣẹwọn lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan kan, eyi to ti sọ ọ dero kootu, to si ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.
Ile-ẹjọ Majisireeti keji to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ ni wọn wọ ọkunrin naa lọ lori ẹsun pe o ṣeku pa obinrin ẹni aadọta ọdun kan, Toyin Ọlatunji.
Agbefọba, Abdulateef Suleiman, ṣalaye ni kootu pe iṣẹlẹ ọhun waye laduugbo Mofẹrere, Owe-Akala, l’Akurẹ, laago mẹta ọsan ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 ta a wa yii.
Suleiman ni olujẹjọ ọhun to jẹ pasitọ ijọ Aposteli ti Krisiti (CAC), kan l’Akurẹ, lawọn agbofinro fi pampẹ ofin gbe nile rẹ lori iku obinrin ti wọn lo jẹ ọkan ninu awọn ayalegbe ti iranṣẹ Ọlọrun naa gba sile.
O ṣalaye pe ọrọ kan lo fẹẹ ṣe bii ija laarin awọn mejeeji lọjọ yii, ti Pasitọ Emmanuel fi binu ti oloogbe ọhun ṣubu, leyii to mu ko daku lọ gbari, ti ko si laju saye mọ titi to fi ku.
Awọn ẹsun yii lo juwe bii eyi to ta ko abala okoolelọọọdunrun din mẹrin (316) ati ọọdunrun le mẹwaa (310) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Agbẹnusọ fun ijọba ọhun waa rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ pe ki wọn fi pasitọ naa pamọ sọgba ẹwọn titi di igba ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Onidaajọ Tọpẹ Aladejana ni ki olujẹjọ ṣi wa ninu ọgba ẹwọn Olokuta, gẹgẹ bii ibeere agbefọba, titi di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ta a wa yii.