Iyiade Oluṣẹyẹ, Akurẹ
Titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn eeyan ṣi n sọ nipa ọkunrin to maa n so bata kan torukọ rẹ n jẹ Sikiru Owolabi to pa ọmọ lanlọọdu ẹ, Bọlanle Adinlewa nitori ọrọ ti ko to nnkan lagbegbe Ijọ Mimọ, to wa niluu Akurẹ.
Isẹ bata ni Sikiru n ṣe gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọdọ baba Bọlanle lo ti rẹnti ṣọọbu to ti n ṣiṣẹ soobata rẹ niluu Akurẹ.
Ọrọ ti ko to nnkan la gbọ pe o ṣẹlẹ laarin ọmọkunrin yii ati Sikiru, ni wọn ba kọju ija sira wọn.
Ki awọn araadugbo too mọ ohun to n ṣẹle, Siiru ti mu afọku igo, ko si fi wọn ọmọkunrin naa wo rara to fi gun un. Bẹẹ ni ẹjẹ bẹrẹ si i ya nibi oju ọgbẹ naa.
Awọn araadugbo ni wọn sare gbe Adinlewa lọ sọsibitu lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ko ti i de ileewosan to fi ku.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayọ Odulami, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn mejeeji jọ n ja ni lasiko tiṣẹlẹ naa waye. O fi kun un pe iiwadii yoo bẹrẹ lori ohun to fa ija laarin wọn to fi yọri si iku ọmọkunrin naa.