Adewale Adeoye
Afi bii eedi lọrọ ọhun jọ leti gbogbo awọn to gbọ ohun ti afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Vincent Upkpai, to pa ayalegbe rẹ kan, Oloogbe Gloria ati ọmọ rẹ, nitori ọrọ ti ko to nnkan ṣe.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni iṣẹlẹ ibanujẹ naa waye lagbegbe Ẹlẹmọrọ, niluu Eko.
ALAROYE gbọ pe ọrọ kekere kan ti ko yẹ ko dija laarin afurasi ọdaran naa ati oloogbe yii lo dija silẹ laarin awọn mejeeji, kawọn araale ibi ti wọn n gbe si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, afurasi ọdaran naa ti ṣinu bi, o ti gbẹmi oloogbe ati ọmọ rẹ to n gbe lọdọ rẹ.
Bo ṣe pa a tan lo ba gbe oku rẹ sinu apo ṣaka nla kan, o fẹẹ lọọ ju u nu ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe ọrọ ilẹ gbigba lo dija silẹ laarin afurasi ọdaran naa ati oloogbe, kawọn araale si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, afurasi ọdaran naa ti pa iyaale ile naa. O gbe oku rẹ sinu apo ṣaka, o fẹẹ lọọ ju u nu.
Awọn araale ni wọn lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa teṣan Ẹlẹmọrọ, niluu Eko leti, tawọn yẹn si waa fọwo ofin mu un lọ sọdọ wọn. Wọn gbe oku oloogbe naa lọ si ọsibitu ijọba to wa niluu Ẹpẹ, lati ṣayẹwo si i, ki wọn le mọ ohun to pa a.
Alukoro ni awọn maa ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, tawọn si maa foju afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ lẹyin iwadii awọn.