Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n kọ haa lori iku ojiji to pa baba kan, Alagba Ndungu Mugachia, ẹni ọdun mọkandinlọgọrun-un (99) ti iyawo rẹ fada bẹ lori lọjọ karun-un, oṣu kẹsan-an yii, labule Kagumo-ini, ni Guusu orilẹ-ede Kenya.
Orukọ iyawo to bẹ ọkọ ẹ lori naa ni Magret Wanjiru, ẹni ọdun marundinlaadọrin(65).
Gẹgẹ bawọn ọlọpaa agbegbe naa ṣe ṣalaye, wọn ni iyawo ọmọ baba yii gbe ounjẹ aarọ fun un pe ko jẹ, Ọlọrun lo waa mọ ohun to de ti eyi ko fi dun mọ iyawo baba ninu, o si bẹrẹ si i bu iyawo ọmọ rẹ naa pe ki lo n fun ọkọ oun lounjẹ fun.
Ija obinrin naa ni baba fẹẹ gbe, to fi da si i pe ki lo de to n bu u, abi ṣe aburu wa ninu kiyawo ọmọ eeyan tun gbe ounjẹ aarọ fun ni jẹ ni.
Ohun to bi iya yii ninu ree o gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi, ada kan ni wọn ni iya to n jẹ Magret yii ki mọlẹ, to si kọkọ fi ge eti ọtun ọkọ rẹ, lẹyin naa lo si gbe ada naa le e lọrun, to dumbu rẹ bii ẹran, to tun ge ori rẹ ja.
Kawọn ọlọpaa too de nigba tawọn araale pe wọn, baba arugbo naa ti dagbere faye. Obinrin to pa a yii ni wọn ri mu lọ si teṣan ọlọpaa Kabati, wọn ni wọn yoo gbe e lọ sile-ẹjọ laipẹ.
Wọn ni wọn yoo ṣayẹwo si oku baba agba naa, ṣugbọn mọṣuari ileewosan Gaichanjiru Catholic Mission ni wọn tọju oku naa si. Nibẹ lo pari ẹ si lẹyin ọdun mejilelaaadọta (52) to ti fẹ iyawo to ran an sọrun apapandodo.