Nitori ounjẹ, Ojo dana sun ọmọ iyawo rẹ marun-un l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Bi eeyan ba jori ahun, ko si ki oluwarẹ ma ṣomi loju poroporo to ba de ile ti baba agbalagba kan, Ojo Joseph, ti dana sun awọn ọmọ iyawo rẹ marun-un nitori owo ounjẹ ẹẹdẹgbẹta Naira niluu Ondo.

Ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla yii la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye ni Ojule kẹtadinlogoji, adugbo Ayesanmi, Odojọmu, l’Ondo.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu araadugbo kan lasiko ta a ṣe abẹwo sibi iṣẹlẹ ọhun nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, pe ọmọ marun-un ni Abilekọ Esther Faṣekomi to jẹ iya awọn awọn naa ti bi fun ọkọ rẹ aarọ ko too kẹru rẹ kuro nibẹ lọsan-an kan oru kan, to si pada waa fẹ Ojo, to si  bimọ ibeji fun oun naa. Ọdọ Esther, nile ọkọ tuntun to ṣẹṣẹ fẹ, lawọn ọmọ maraarun-un to bi fun ọkọ aarọ rẹ n gbe.

Ojo ni wọn lo kọ ile naa, ṣugbọn ki i ba wọn gbe ibẹ, yara kan pere si lọkunrin to n ṣiṣẹ gẹdu ọhun ati iyawo rẹ n gbe ninu ojule mẹjọ to wa ninu ile ọhun. Inu yara naa loun, iyawo rẹ atawọn ibeji to ṣẹṣẹ bi fun un n sun lalẹ, nigba to jẹ pe gbagede ọdẹdẹ ile ọhun lawọn ọmọ iyawo maraarun-un n tẹni si lati sun ni tiwọn.

Ọpọ awọn araadugbo ni wọn jẹrii si i pe gbogbo igba ni tọkọ-taya naa maa n ba ara wọn ja lori ọrọ ounjẹ ati ibalopọ laarin awọn mejeeji.

Mama agbalagba kan ta a forukọ bo laṣiiri jẹ ko ye wa pe ketekete lawọn maa n gbọ ariwo wọn laduugbo ti wọn ba ti n ba ara wọn ja, o ni awọn tun gbọ bi wọn ṣe n ja lalẹ ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja.

Wọn ni ni nnkan bii aago mẹta oru ni Ojo yọ kẹlẹkẹlẹ dide kuro lẹgbẹẹ iyawo rẹ to sun si, to si lọọ wọn epo bẹntiroolu to ti gbe pamọ le awọn ọmọ iyawo rẹ lori nibi ti wọn sun si, ko too sana si i.

Ọkàn ninu awọn olugbe ile ọhun lo gbọ ti awọn ọmọ naa n pariwo, ‘ina o, ina o’, to si sare jade lati inu yara rẹ lati doola ẹmi wọn.

Awọn mẹrin ni wọn ri ko jade ninu ina ọhun laaye, nigba ti ẹni karun-un wọn ti ku sinu ina ki wọn too mọ pe o wa nibẹ.

Aarin oru naa ni wọn ti sare gbe awọn ọmọ naa lọ si ile-iwosan ijọba to wa niluu Ondo, lati ibẹ ni wọn ti ko wọn lọ si ọsibitu ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ, ṣugbọn ti ọkan ninu awọn ọmọ naa tun pada ku ki wọn too de ọhun.

A gbiyanju lati ṣawari Ọgbẹni Ṣeun Afọlayan, ẹni ti wọn ni Ọlọrun lo lati doola ẹmi awọn ọmọ naa nigba ti ina n jo wọn lọwọ. Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Kwara ọhun ṣalaye fun akọroyin wa pe ẹgbẹ ẹnu ọna yara oun ni awọn ọmọ naa maa n sun lalaalẹ.

Lojiji lo ni oun n gbọ ariwo ina, loru ọganjọ, o ni oun kọkọ ro pe ṣe ni wọn ti mu ina NEPA wa ni, ṣugbọn nigba toun bẹrẹ si i ni imọlara gbigbona ooru ina ninu yara loun  fo dide, toun si lọọ silẹkun lati wo ohun to sẹlẹ.

O ni oun gan-an ko kọkọ mọ ọna ati jade, latari ina to ti gba ẹnu ọna yara naa kan, Ṣeun ni inu ina ọhun loun pada gba jade, ti oun si bẹrẹ si i gbe awọn ọmọ naa lọkọọkan titi oun fi ri mẹrin gbe ninu wọn.

Lẹyin ti wọn pa ina ọhun tan patapata lo ni oun ṣẹṣẹ mọ pe ẹni karun-un wọn ti ku sinu ina.

O ni loootọ ni tọkọ-taya naa saba maa n ba ara wọn ja, to si jẹ pe gbogbo araadugbo lo ti pa wọn ti si tiwọn, ọrọ ounjẹ ati ibalopọ lo ni oun mọ pe o maa n di ja silẹ laarin wọn.

Ni ti ija to waye kẹyin laarin wọn lalẹ ọjọ Ẹti, Furaide, to kọja, o ni Ojo fun iyawo rẹ ni ẹẹdẹgbẹta Naira pere ko fi wa ounjẹ silẹ de oun nigba to fẹẹ jade. Ija nla lo ni ọkunrin to n ṣiṣẹ igi gẹdu ọhun gbe ko iyawo rẹ loju nigba to pada de ti ko ba ounjẹ nilẹ, o ni oun atawọn eeyan kan ba wọn da si ọrọ naa, ti awọn si ba wọn yanju rẹ lai mọ pe ko tan rara ninu rẹ.

O ni ọkan ninu awọn ọmọ naa ti ko ti i sun wọra lo n pariwo pe oun ri Ojo to jẹ ọkọ iya awọn nigba to n wọn epo bẹntiroolu si awọn lara ko too sana si i.

Ninu ọrọ ti Ọgbẹni Akinfọlarin Liadi to jẹ baba awọn ọmọ naa ba wa sọ, o ni nnkan bii aago mẹrin idaji ni wọn pe oun pe ile ti awọn ọmọ oun n gbe ti n jona. O ni oun ko fi bẹẹ ka ọrọ naa si títi ti ọkan ninu awọn ọmọ oun to n jẹ Bisọla fi pe oun funra rẹ ni nnkan bii aago mẹfa aarọ pe ki oun tete maa bọ nitori pe awọn ti jona.

Ọgbẹni Liadi ni iṣẹ awọn to n fi katapila ko igi gẹdu jade lati inu igbo loun n ṣe, o ni aikii gbele oun loun fi gba kawọn ọmọ naa maa gbe lọdọ iya wọn, gbogbo ọjọ Abamẹta, Satide, ti oun ba ti wale lo ni awọn ọmọ naa maa n wa sọdọ oun, ti oun si maa n fun wọn lowo ati ounjẹ.

O ni awọn ọmọ marun-un ọhun nikan loun bi laye lọrun, ọkunrin yii ni ṣe loun mọ-ọn ma fẹ iyawo mi-in lati igba ti iya wọn ti funra rẹ kẹru jade nile oun nitori iye ọmọ ti oun bi ti tẹ oun lọrun.

Baba ẹni aadọta ọdun ọhun ni oun ti n tu owo jọ tẹlẹ lati waa ra ọkada ti oun fẹẹ maa fi ṣiṣẹ koun le raaye bojuto awọn ọmọ oun ki ajalu buruku naa to waye.

O ni ko sohun meji to dija oun ati iya wọn ju irinkurin ati iṣekuṣe to n ṣe lọ.

Awọn meji to ku ninu awọn ọmọ maraarun-un, iyẹn Aanu, ọmọ ọdun mẹsan-an ati Tayọ, ọmọ ọdun meje, to jẹ abikẹyin wọn. O ni awọn mẹta yooku ṣi wa nile-iwosan ijọba apapọ niluu Ọwọ, nibi ti wọn ti n gba itọju. Meji ninu wọn lo ni wọn wa lẹsẹ-kan -aye, ẹsẹ-kan-ọrun pẹlu afẹfẹ gaasi ti wọn fi n mi.

Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni Ojo ṣi wa nikaawọ awọn, nibi ti awọn ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo. O ni ọkunrin naa yoo foju bale-ẹjọ nigba ti iwadii ba pari lori ọro rẹ.

Leave a Reply