Nitori owo iranwọ epo ti wọn yọ, awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ yoo maa wọkọ ọfẹ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lati mu ki irọrun de ba awọn araalu, paapaa ju lọ awọn oṣiṣẹ ijọba, pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori nitori owo iranwọ epo ti wọn yọ, Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulraman AbdulRazaq, ti sọ pe lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ Kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni awọn akẹkọọ nileewe giga nipinlẹ naa, paapaa ju lọ ileewe giga yunifasiti wọn, Kwara State University  (KWASU), atawọn oṣisẹ ijọba lawọn ileewe ọhun yoo bẹrẹ si i maa wọkọ ọfẹ lọ sibi iṣẹ wọn laarin inu ilu Ilọrin ati gbogbo agbegbe rẹ.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ Kọkanla, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni AbdulRazaq fi atẹjade yii lede fawọn oniroyin latọwọ Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye.

Ninu atẹjade naa ni gomina ti sọ pe lati Ọjọruu, Wẹsidee, ijọba yoo ko awọn bọọsi nla sawọn aaye kan niluu Ilọrin, ti yoo maa ko awọn akẹkọọ nileewe giga atawọn oṣiṣẹ wọn lọ si ileewe wọn lọfẹẹ fun irọrun lilọ bibọ wọn. AbdulRazaq tẹsiwaju pe gbogbo ọna ni oun yoo san lati ri i pe irọrun de ba awọn oṣiṣẹ ati gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lapapọ, ti eto ọrọ aje ipinlẹ naa yoo si maa gberu si i. O fi kun un pe laipẹ, awọn adari ileeṣẹ nipinlẹ naa yoo maa sọ ẹkunrẹrẹ nipa eto yii kan naa.

Leave a Reply