Faith Adebọla, Eko
Titi di ba a ṣe n sọ yii, titi lawọn geeti meejeji to wọ ọgba ileeṣẹ ajọ olomi ipinlẹ Eko (Lagos State Water Corporation) to wa lagbegbe Ijọra wa. Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa lo ṣa geeti ọhun ni agadagodo lati aago mẹjọ owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, wọn si lawọn ko ni i ṣi i, afi tijọba ba san owo-oṣu awọn.
Oriṣiiriṣii akọle ni wọn lẹ mọ ara geeti ọgba naa, ti wọn si n kọrin lati fi aidunnu wọn han si bijọba ṣe jẹ wọn lowo-oṣu bii mẹta sẹyin, yatọ si ọpọ ajẹmọnu ti wọn lẹtọọ si.
Lara awọn akọle naa ka pe: “O to gẹẹ, ijiya yii o tọ si wa nileeṣẹ ajọ olomi,” “Ẹ jawọ ninu ipetepero lati bi ileeṣẹ ajọ olomi Eko ṣubu,” “Ẹ yee fowo ajọ olomi Eko ṣe apasapo mọ,” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọgbẹni Abiọdun Bakare, to jẹ Akọwe agba fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba atoniṣẹ-ọwọ (Amalgamated Union of Public Corporations, Civil Service, Technical and Recreational Services Employees,) AUPCTRE, sọ fun ajọ akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, pe iyanṣẹlodi tawọn oṣiṣẹ olomi naa gun le bayii ko ni i dopin, titi ti ijọba yoo fi san ẹtọ awọn oṣiṣẹ wọnyi, o ni niṣe nijọba Eko mọ-ọn-mọ yan ajọ olomi nipọsin, ti wọn n fun awọn ẹka ileeṣẹ mi-in lafiyesi lai ri tiwọn ro.
O fikun un pe ọpọ adehun ni gomina ti ba awọn ṣe, sibẹ to jẹ otubantẹ lasan ni, ati pe ijọba fẹẹ gbọna ẹyin sọ ileeṣẹ naa di ti aladaani leyii ti ko bofinmu mu.
A gbiyanju lati ba Alukoro ajọ naa sọrọ, ṣugbọn nọmba wọn ko lọ.