Nitori owo Tinubu, ẹgbẹ APC ati PDP Ọṣun sọko ọrọ sira wọn 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe ti Gomina Ademọla Adeleke ko ba le kede eto to ni gẹgẹ bii palietiifu fawọn araalu, ko bojumu kijọba rẹ tun pa ika mọ bìliọnu meji Naira tijọba apapọ fi ranṣẹ.

Alaga ẹgbẹ naa, Sooko Tajudeen Lawal, sọ nipasẹ alakooso iroyin wọn, Oloye Kọla Ọlabisi, pe o jẹ ohun to buru ki ijọba ipinlẹ kankan lorileede yii maa huwa to le mu ki awọn araalu korira ijọba apapọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ohun ti ko ṣee gbọ ni pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ko biliọnu meji Naira tijọba apapọ fi ranṣẹ gẹgẹ bii palietiifu fawọn araalu pamọ lati oṣu meji sẹyin ti wọn ti gba a.

O ni ko si awijare kankan tijọba Adeleke ni lori ohun ti wọn ṣe yii nitori ṣe ni wọn mọ-ọn-mọ n fara ni awọn araalu, ko si sẹni to mọ boya wọn n reti ki awọn eeyan bẹrẹ si i ku ki wọn too pin owo naa.

Ṣugbọn nigba to n fesi, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Sunday Bisi, sọ pe alainitiju lẹgbẹ APC, nitori ko yẹ ki wọn lẹnu ọrọ mọ pẹlu ọgbun gbese ti wọn ti ipinlẹ Ọṣun si ki wọn too kogba wọle.

Sunday Bisi ṣalaye pe ẹgbẹ PDP ki i ṣe ẹgbẹ alajẹbanu bii tiwọn. O ni adari to bọwọ fun akoyawọ ni Gomina Adeleke, o si ti ranṣẹ ọpọlọpọ nnkan to wa fun iranwọ fun awọn araalu, laipẹ ni gbogbo aye yoo si ri i.

O ni awọn nnkan palietiifu naa pọ debii pe yoo lọ kaakiri tibu-tooro ipinlẹ Ọṣun, awọn ti awọn araalu si fi ibo wọn le danu nitori iwa ole wọn nikan ni wọn le maa ro pe gomina to wa lati idile olowo yoo dẹbiti aya de owo palietiifu.

O kilọ fun ẹgbẹ APC Ọṣun lati dẹkun sisọ ọrọ alufansa kaakiri nipa iṣẹjọba to wa lode, nitori awọn ko ni i kuna lati gbe igbesẹ to tọ lori wọn ni ibamu pẹlu ofin lọjọ ti wọn ba tun hu iru iwa bẹẹ.

Leave a Reply