Adewale Adeoye
Bọrọ tawọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ lorileede wa n sọ ba jẹ ootọ, Ọjọruu, Wesidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni wọn sọ pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi jake-jado orileede yii, nitori ọrọ owo iranwọ epo bẹntiroolu tijọba apapọ kede rẹ pe awọn ti yọ kuro, eyi to ti mu ki gbogbo nnkan gbowo lori, ti awọn araalu si n koju inira nla.
Atẹjade pataki kan ti Akowe agba ajọ naa, Kọmureedi Emmanuel Ugboaja, fi lede lẹyin ipade ẹgbẹ naa, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe ko sohun to le di awọn lọwọ lati ma ṣe bẹrẹ iyanṣelọdi naa lọsẹ to n bọ gẹge bii ipinnu awọn oloye ẹgbẹ naa lori ohun ti ijọba apapo ṣe nipa bi wọn ṣe yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu kuro.
Bakan naa ni wọn rọ gbogbo awọn olori ẹka ileeṣẹ gbogbo ti wọn jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ ajọ oṣiṣẹ nilẹ yii pe ki wọn gbaruku ti eto naa, ko baa le kẹsẹjari layọ ati alaafia bayii.
Apa kan lẹta ọhun to tẹ ileeṣe ALAROYE lọwọ ka pe: ‘A ti gbe e yẹwo daadaa, igbesẹ ijọba apapọ lori bo ṣe yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu ọhun ki i ṣohun to daa rara, a ko ni i gba fun wọn, bijọba ko ba tete yi ipinnu rẹ pada lori ọrọ naa, gbogbo oṣiṣe nilẹ yii pata ni wọn yoo gun le eto iyanṣelodi lọsẹ to n bọ. Ko sohun naa to le da wa duro rara pe ka ma bẹrẹ iyanṣẹlodi. A n fi asiko yii rọ gbogbo awọn ojulowo ajọ oṣiṣẹ nilẹ yii pe ki wọn wa ni igbaradi fun eto naa lọsẹ to n bo. Jake-jado origun mẹrẹẹrin orileede yii ni awọn oṣiṣẹ yoo ti daṣẹ silẹ.’