Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kayeefi lọrọ naa ṣi n jẹ fun awọn eeyan, nitori o ṣoro pupọ fawọn mi-in lati gbagbọ pe ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹwaa pere le ronu ati binu ju aburo rẹ sinu kanga nitori owu jijẹ.
Pupọ eeyan ni wọn ka iṣẹlẹ yii si ahesọ lasan, afi igba tawọn ọlọpaa too ṣafihan ọmọbinrin ọhun, ẹni ti wọn porukọ rẹ ni Suliya Abubakar ni olu ileesẹ wọn to wa ni Alagbaka, lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, lo ṣẹṣẹ han sawọn to n siyemeji pe loootọ ni.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, iyawo meji ni Ọgbẹni Abubakar to jẹ baba Suliya fẹ, iya rẹ bimọ meji pere, iyẹn Suliya ati aburo rẹ kan, nigba ti iyawo keji bimọ bii meje.
Ọsẹ to kọja yii lo ki ọkan ninu awọn ọmọ iyawo ti wọn fẹ le iya rẹ, Usman Abubakar, mọlẹ, to si ju u sinu kanga lai fu ẹnikẹni lara.
O kọkọ parọ fun baba rẹ pe awọn ajinigbe kan lo ji ọmọ naa gbe nigba to ṣakiyesi pe wọn ti n wa ọmọ to ṣeku pa ọhun.
Funra rẹ lo tun pe baba rẹ jokoo, to si jẹwọ pe oun loun ju u si kanga nitori pe inu oun ko dun bi baba awọn ṣe n fun ọmọ naa nitọju ju ti awọn yooku lọ.
Lẹyin eyi ni wọn fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti loju ẹsẹ to ti jẹwọ fun baba rẹ, awọn ni wọn si wa gbogbo ọna ti wọn fi gbe oku ọmọ naa kuro ninu kanga.
Ọdọ awọn ọlọpaa lọmọbinrin naa ṣi wa ni gbogbo asiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.